Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọsẹ to kọja ni aṣiri Pasitọ Oyebọla to ba ọmọ bibi inu ẹ sun fọdun marun-un tu saye nipinlẹ Ogun, pasitọ mi-in torukọ tiẹ n jẹ Oketokun Abiọdun lọwọ awọn ọlọpaa tun tẹ bayii l’Ọdẹda, ipinlẹ Ogun kan naa. Ọmọ ọdun mẹwaa pere loun ki mọlẹ lọjọ kẹwaa, oṣu yii, o si fipa ba a lo pọ̣ titi to fi fa a labẹ ya.
‘Light Christian Church’ ni orukọ ṣọọṣi ti Oketokun ti jẹ pasitọ, l’Ọdẹda, ẹni ọdun mọkandinlọgọta(59) ni baba naa.
Alaye ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ yii, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ALAROYE ni pe baba to bi ọmọ ọdun mẹwaa naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Owode pe Pasitọ Oketokun ri ọmọ oun to n ṣere pẹlu awọn ọmọde ẹgbẹ ẹ lọjọ naa, o si pe e laarin wọn pe ko lọọ ba oun mu kọkọrọ yara oun wa ninu ile.
Kọkọrọ yara Oketokun lọmọ naa fẹẹ lọọ ba a mu ti pasitọ fi tẹle e lẹyin, bi ọmọdebinrin naa ṣe wọle ni Oketokun paapaa wọle tọ ọ, o ti ọmọ ọdun mẹwaa naa lu bẹẹdi, o fọwọ bo o lẹnu, o si ba a laṣepọ tipatipa lọsan-an gangan.
O ti ṣere buruku naa tan kawọn eeyan too mọ pe nnkan ti ṣe, igba ti baba ọmọ si ri ohun ti pasitọ ṣe fọmọ rẹ lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan, to fi di pe awọn ọlọpaa waa gbe Oketokun.
Nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, baba to fipa ba ọmọde naa sun yii jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ ọdun mẹwaa yii lo pọ, ẹnikẹni ko purọ mọ oun.
Lasiko ti a kọ iroyin yii lọwọ, teṣan Ọdẹda naa ni wọn ṣi fi baba agbalagba yii pamọ si, ṣugbọn pẹlu aṣẹ CP Kenneth Ebrimson ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, wọn ko ni i pẹẹ gbe e lọ sẹka to n ri si lilo ọmọde nilokulo.
Church wo ni pasito náà wà?
Kiwon yegi fun