Faith Adebọla
Ko sọna ti Kome Ọgaga, iyẹn ọkunrin tẹ ẹ n wo fọto ẹ yii, ko fi ni i rojọ arogbẹmi-aya, yoo rojọ, ẹnu ẹ aa fẹrẹ bo ni kootu, afaimọ si lọrọ rẹ ko ni i ba ẹwọn fọpa-wọn lọ, iyẹn bi wọn o ba ni ki wọn lọọ pa a nigbẹyin. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o yinbọn pa ọmọọlọmọ, Merrit Hossana, ọmọọdun mọkanla, nibi ti afurasi ọdaran yii ti ni koun tẹẹsi ibọn agbelẹrọ kan to ṣẹṣẹ ra, wo.
Ilu kan ti wọn n pe ni Ozoro, nijọba ibilẹ Ariwa Isoko, nipinlẹ Delta, niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja lọhun-un.
Alaye ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Delta, James Edafe, ṣe lọjọ Tusidee, ọsẹ yii, ni pe awọn aladuugbo kan ni wọn waa fẹjọ sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta pe iṣẹlẹ aburu kan ti waye, Kome ti yinbọn pa Hossana, lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ.
Awọn ti wọn ri ohun to ṣẹlẹ sọ pe awọn o mọ ibi to ti ri ibọn ilewọ pompo ọhun, ṣugbọn ibọn tuntun ni, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ibọn oyinbo.
Ṣe aṣọ tuntun ni i ṣe olowo ẹ ni roderode, ibọn tuntun to tẹ ẹ lọwọ yii lo ni koun gbọ iṣẹ ẹ wo, lo ba rọ ẹtu ati ọta si i, o ki i, o si tawọ si adodo ẹ, n lakọ irin ba fọhun akin gbola.
Ṣugbọn Yoruba bọ, wọn ni ọmọ ire ko si ninu ibọn, inu igbo etile ni Kome yinbọn si, b’ariwo ibọn ṣe n rọlẹ, igbe ọmọde to n ṣere tiẹ lo tẹle e, ibọn ti ba a, oju-ẹsẹ lo ti n ja raparapa nilẹ bii ejo to ṣẹ lẹyin, o n pọkaka iku, nigba toro ibọn mu un.
Eyi ti afurasi naa iba si fi duro ṣaajo diẹ, wọn ni niṣe ni jagunlabi ta kọṣọ sinu igbẹ, lo ba na papa bora, o sa lọ rau. Atigba naa ni wọn ti n wa a, ti wọn ko si ri i nile.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọjọ, oṣu yii, lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ba a nile ọrẹ rẹ kan, nibi to sa pamọ si, awọn ọlọpaa fẹrẹ ma da a mọ mọ, tori irun dada lo gbe sori ko too yinbọn, ṣugbọn o ti gẹrun naa kuro, boya nitori ki wọn ma le tete mọ poun ni, ni wọn ba fi ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, wọn mu un lọ sahaamọ ọlọpaa.
Nigba ti wọn lọọ ṣayẹwo ile ẹ, wọn ri ibọn naa nibẹ, o loun ṣẹṣẹ ra a ni, oun fẹ tẹẹsi ẹ wo ni ọta ibọn naa fi ṣeeṣi ba ọmọ to doloogbe naa.
Wọn tun bi i pe ki lo fẹẹ fi ibọn ṣe, n lọrọ ba pesi jẹ, ko dahun, niṣe lo dorikodo, to n wo su u.
Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, Edafe ti sọ pe laipẹ ni Kome ati ibọn tuntun ẹ maa fara han niwaju adajọ, lati gba idajọ to tọ si wọn.