Kọmiṣanna ṣafihan okoolelẹẹẹdẹgbẹta awọn ti wọn lọwọ ninu rogbodiyan SARS l’Ekoo

Aderohunmu Kazeem

Okoolelẹẹẹdẹgbẹta (520) awọn eeyan ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ṣafihan wọn ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe wọn lọwọ ninu iwa janduku, ole jija, ija igboro, dida omi alaafia ilu ru, jija awọn araalu lole ohun ini wọn ati bẹẹ beẹ lọ lasiko rogbodiyan ifẹhonu han SARS to waye niluu Eko.

Kọmiṣanna sọ eleyii di mimọ lasiko to n ṣafihan awọn eeyan ọhun fun awọn oniroyin ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ikẹja. O ni awọn janduku yii yoo foju bale-ẹjọ pẹlu bi wọn ṣe ja iwọde ifopin si SARS ọhun gba, ti wọn si fi dalu ru.

‘‘Nigba ta a ri i bi nnkan ṣe n lọ, kiakia ni ileeṣẹ ọlọpaa ya si igboro nigba ta a ṣakiyesi pe ọrọ naa ti kuro ni ifopin si SARS pẹlu bi wọn ṣe n dana sun dukia, ti ẹmi awọn araalu si n lọ si i. A woye pe awọn janduku ti ja ifẹhonu han naa gba lọwọ awọn ti wọn n ṣe e. Eyi lo jẹ ka jade, ti a si ri ọpọ awọn nnkan ti awọn janduku naa ji ko gba pada lọwọ wọn, ti a si fọwọ ofin mu awọn ti wọn ṣiṣẹ buruku naa.

‘‘Ni bayii, okoolelẹẹẹdẹgbẹta awọn janduku yii la ti mu fun ẹsun loriṣiiriṣii bii idaluru, iwa janduku, ipaniyan, biba nnkan awọn eeyan jẹ ati nini ohun ija oloro lọwọ.’’

Kọmiṣanna ni laipẹ ni awọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply