Kọmiṣanna Ambode fi ẹgbẹ APC silẹ, o loun naa fẹẹ di gomina  Eko

Adeounmu Kazeem

Ọkan lara awọn komiṣanna to ba gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Akinwunnmi Ambọde ṣiṣe, Ọnarebu Abdul-Lateef Abdul-Hakeem ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC bayii.

Ohun to mu ọkunrin oloṣelu yii kuro ni bo ti ṣe fi ifẹ han lati dije dupo gomina lọdun 2023, eyi to sọ pe ko dun mọ awọn agbaagba kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC. O ni, iyẹn gan-an lo mu oun yẹra bayii, ki igbesẹ oun yii ma da wahala silẹ ninu ẹgbẹ.

Nigba ti Ọnarebu Lateef n ṣe ifilọlẹ Iyẹpẹ 2023 lo sọrọ yii fawọn oniroyin. Bakan naa lo sọ pe, bi oun ti ṣe kuro ninu ẹgbẹ, oun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati faaye gba awọn eeyan oun ti wọn ṣi wa pẹlu wọn, ki wọn ma ṣe tori wi pe oun ko si pẹlu wọn mọ fara ni wọn ninu ẹgbẹ.

Ninu ọrọ ẹ naa lo tun ti sọ pe ọmọ ipinlẹ Eko loun, ati pe oun letọ daadaa labẹ ofin lati ko eeyan jọ lori erongba oun lati dupo oṣelu, pẹlu ojuṣe agbekalẹ eto ati ilana to tọ fun wọn nipa ijọba dẹmokiresi, eyi to le mu aye rọrun fun tẹru-tọmọ.

Ọnarebu Yẹpẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n pe e, ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin Eko nigba kan ri, bẹẹ lo tun jẹ olubadamọran fun olori ile igbimọ aṣofin Eko, Mudashiru Ọbasa.

Ọkunrin oloṣelu yii ti waa dupẹ lọwọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, Ọladele Ajọmale, Tunde Balogun atawọn ẹlomi-in ninu ẹgbẹ. O ni, ipa nla ni Tinubu ko nipa bi oun naa ṣe fẹsẹ rinlẹ daadaa ninu oṣelu loni-in.

 

Leave a Reply