Kọmiṣanna eto ẹkọ ti ko si nipinlẹ Ogun n fa wa sẹyin-Ẹgbẹ Akẹkọọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Apapọ ẹgbẹ akẹkọọ nipinlẹ Ogun, ‘National Association of Ogun State Students’ (NAOSS), ti fi aidunnu wọn han si bi ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ko ṣe ti i yan kọmiṣanna eto ẹkọ latigba ti wọn ti yọ Arabinrin Sidi Ọshọ kuro. Wọn ni ifasẹyin gidi ni eyi jẹ fawọn.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Kọmureedi Oluwagbemileke Ogunrombi, ati Kọmureedi Tọmiwa Bamgboṣe to jẹ alaga ẹgbẹ akẹkọọ nipinlẹ Ogun, ni wọn jọ fi atẹjade to n kede ẹdun ọkan wọn naa sita l’Ọjọbọ, Tọsidee to kọja. Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe ko si ijọba gidi to n fẹ idagbasoke lẹka ẹkọ ti ko ni i yan kọmiṣanna fun abala naa.

‘‘Ẹka ẹkọ gẹgẹ bii abala pataki, yẹ ko ri gbogbo amojuto to nilo gba lọdọ ijọba. Bi ko ṣe si kọmiṣanna ẹkọ yii n ṣakoba fun ẹkọ nipinlẹ yii gan-an. O ṣe pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lati tete yan kọmiṣanna kan gboogi fun ileeṣẹ eto ẹkọ, eyi ti yoo jẹ ki afojusun ijọba wa si imuṣẹ’’.

‘’Latigba ti wọn ti yọ Ọjọgbọn Sidi Ọshọ kuro nipo ni gomina ti kọ lati yan ẹlomi-in, eyi si n fa ọwọ aago idagbasoke ẹka yii sẹyin.’’

Wọn waa ni bijọba yoo ba yan kọmiṣanna fawọn, purofẹsọ lo gbọdọ jẹ, nitori ipinlẹ Ogun ni awọn ọjọgbọn to pọ gidi.

Bakan naa ni wọn fi kun un pe inu awọn ko dun si bijọba ipinlẹ Ogun ko ṣe fi awọn akẹkọọ sinu igbimọ to n ri si ṣiṣi ileewe pada nipinlẹ Ogun. Wọn ni bii igba tijọba n fari lẹyin olori ni igbesẹ ijọba yii, nitori awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan ni ijọba ko fi ẹnikankan ninu wọn si igbimọ rẹ yii.

Lati mọ iha ti ijọba kọ sawọn ẹsun yii, akọroyin wa pe Abilekọ Ronkẹ Ṣoyọmbọ, Oludamọran Pataki fun gomina lori ọrọ ẹkọ nipinlẹ Ogun, ṣugbọn obinrin naa sọ pe oun n wa mọto lọwọ. Nigba ta a fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i pe ko sọrọ lori ṣiṣi ileewe nipinlẹ Ogun, obinrin yii ko da esi pada titi ta a fi pari iroyin yii.

 

Leave a Reply