Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun: Mọto ọlọpaa to ko irẹsi tawọn kọsitọọmu gba lọwọ awọn onifayawọ ki i ṣe tiwa o

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ni inu awọn ko dun si ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lasiko yii. Wọn ni ileeṣẹ kọsitọọmu, ẹka ti ipinlẹ Ogun ṣafihan kan laipẹ yii pe ọkọ ọlọpaa, ti wọn so nọmba ileeṣẹ ọlọpaa mọ, wa lara awọn mọto tawọn mu ti wọn fi n ṣe fayawọ irẹsi, wọn lọrọ naa ki i ṣe ootọ, ko si dun m’awọn ninu rara.

Wọn ni ẹka ileeṣẹ kọsitọọmu Ogun 1 Area Command, lo ṣafihan awọn ẹru fayawọ ti wọn ṣẹṣẹ ri gba fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta yii, lolu-ileeṣẹ wọn l’Abẹokuta. Asiko naa ni wọn ṣafihan ọkọ akẹru kan ti nọmba rẹ jẹ PF-10889-SPY, wọn ni apo irẹsi mẹtadinlọgbọn ni ọkọ naa ko, ẹru fayawọ si ni.

Ninu atẹjade kan lori iṣẹlẹ yii ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun buwọ lu lorukọ Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Bankọle, lo ti sọ pe “ko wu ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe fa-a-ka-ja-a pẹlu ileeṣẹ ijọba bii tiwa, ṣugbọn dandan ni ka pe owe lowe, ka si pe ọwẹ lọwẹ lori ọrọ yii, a ni lati ṣalaye ohun to ba ruju nipa ẹ.

“Lakọọkọ, nọmba ti wọn so mọ ọkọ yii, PF-10889-SPY, ki i ṣe nọmba ọkọ ileeṣẹ ọlọpaa rara, ko si ọkọ ọlọpaa kan to ni nọmba naa, a ti ṣayẹwo rẹ daadaa.

“Ohun ti iba daa ju fun awọn kọsitọọmu lati ṣe ni pe ki wọn kọkọ fọrọ yii to olu-ileeṣẹ ọlọpaa leti, tori ko sẹni to maa di wọn lọwọ lati ṣe bẹẹ, ki wọn si ṣewadii hulẹhulẹ nipa ọkọ naa, nọmba ara ẹ, lati mọ boya ọkọ ọlọpaa ni loootọ, ki wọn too pe awọn oniroyin, paapaa nigba ti wọn o ri ẹnikẹni mu ninu ọkọ naa to le sọ bi ọrọ mọto yii ṣe jẹ fun wọn.

“Ileeṣẹ ọlọpaa n fi asiko yii sọ fẹyin araalu pe awa kọ la ni mọto ti wọn n sọ yii o, ki i ṣe mọto ọlọpaa, agbelẹrọ ni nọmba ara ẹ, ko si kan wa lọwọ lẹsẹ rara.”

Bẹẹ ni kọmiṣanna ọlọpaa Ogun sọ.

Leave a Reply