Kọmiṣanna feto Ilera l’Ekoo, Akin Abayọmi, ti ni Korona

Faith Adebọla, Eko

Owe Yoruba kan lo sọ pe ‘Oju ti oniṣegun t’ọmọ ẹ ku lọsan-an, ṣe ewe ni yoo ni oun ko ri ja ni, abi egbo ni yoo ni oun ko ri wa’ Eyi gan-an lo ṣẹ mọ Kọmiṣanna feto Ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, toun naa ti ni arun Korona bayii.

Abajade esi ayẹwo ti wọn ṣe fun ọkunrin naa fihan pe o ti fara kaaṣa arun aṣekupani Koronafairọọsi.

Kọmiṣanna feto iroyin ati ọgbọn-inu, Gbenga Ọmọtọshọ, lo kede ọrọ yii lori ikanni agbọrọkaye ẹyẹnkọrin (tuita) rẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, o ni esi ayẹwo Koro ti wọn ṣe fun Purofẹsọ Abayọmi lopin ọsẹ fi han pe o ti lugbadi arun ọhun. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ itọju ilera ti n tọju rẹ bayii.

Ọmọtọshọ ni nibaamu pẹlu alakalẹ ijọba lori arun yii, Ọjọgbọn Abayọmi maa lọ fara pamọ, o maa wa ni iyasọtọ fun ọjọ mẹrinla gbako, bẹrẹ lati oni, ṣugbọn eyi ko sọ pe ko ma ṣe awọn iṣẹ rẹ, o kan jẹ pe ibi iyasọtọ naa lo ti maa maa ṣe e ni, yoo si maa ṣe awọn mi-in lori ẹrọ ayelujara, tori oun ṣi ni igbakeji awọn to n mojuto arun Korona nipinlẹ Eko, yatọ si ojuṣe rẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti arun Korona ti bẹ silẹ ni Naijiria, to si jẹ ilu Eko ni ayẹwo ti fi ọkunrin oyinbo ara Italy to ko arun ọhun wọlu han lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii, ni Kọmiṣanna Abayọmi mi ti n paara ibudo itọju awọn to lugbadi arun ọhun, to n ṣabẹwo si wọn, ti wọn si n ṣe ọpọ akitiyan lati dẹkun arankalẹ rẹ.

Leave a Reply