Kọmiṣanna ọlọpaa ṣafihan awọn janduku tọwọ ba l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Oriṣiiriṣii ẹsun iwa ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe awọn ba lọwọ awọn janduku lọkunrin lobinrin tọwọ wọn ba lati ọsẹ to pari sasiko yii, gbogbo wọn ni wọn si ti n ṣalaye ara wọn lakolo awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Nibi afihan awọn afurasi ọdaran ọhun to waye lọgba olu ileeṣẹ ọlọpaa Eko, n’Ikẹja, lọjọ Aje, Mọnde yii, lọrọ naa ti waye. Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu,  ṣalaye nipa awọn afurasi naa.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lọwọ ba awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun meji, Sheriff Haruma, ẹni ọdun mejilelogun ati Dare Gabriel, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ti wọn n gbe ni Erekuṣu Snake, l’Ekoo. Agbegbe Igbolosun lọwọ ti ba wọn, wọn jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ lawọn, wọn si ka ibọn ilewọ kan mọ Gabriel lọwọ ni tiẹ.

Ibi tawọn gende mejeeji yii ti n ja ija agba lọsan-an ọjọ naa lawọn kan ti ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, ti wọn fi ri wọn mu.

Bakan naa lọwọ ba Precious Chukwu, ẹni ọdun mejilelogun ati Ujunwa Offiah, ọmọ ọdun mejidinlogun pere. Obinrin lawọn mejeeji yii, niṣe ni wọn gbimọ-pọ pẹlu ọkunrin kan to sikẹta wọn, Ifesinachi Blessed, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ti wọn lo n ṣiṣẹ awakọ UBER, lati dibọn bii ajinigbe, ki wọn le gbowo lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

Njunwa ni wọn tọju pamọ sibi kan, ni wọn ba n pe awọn mọlẹbi ẹ lori foonu pe awọn ti ji ọmọ wọn gbe, miliọnu lọna ọgbọn naira lawọn yoo si gba ko too le dominira.

Abalọ ababọ, wọn pari ọrọ si ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira (#700,000), wọn si juwe ibi ti wọn maa lọọ gbe owo naa si fawọn, lai mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ sode.

Ọjọ ti wọn n reti ati gba owo yii lawọn ọlọpaa ko wọn nibi ti wọn fi ṣe ibuba wọn, laṣiiri ba tu pe wọn mọ-ọn-mọ huwa buruku naa ni, ni wọn ba dero ahamọ.

Ṣugbọn Ifesinachi ribi sa lọ ni tiẹ, wọn ṣi n wa a titi di ba a ṣe n sọ yii, bo tilẹ jẹ pe Hakeem Odumosu to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa Eko ti sọ pe ko roogun ẹ ṣe, awọn maa ri i mu laipẹ.

Bakan naa lọwọ awọn agbofinro tun tẹ awọn mẹsan-an mi-in ti wọn fẹsun pe wọn mọ nipa bi wọn ṣe dana sun sẹkiteria Ijọba Ibilẹ Ajeromi Ifẹlodun logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lasiko rogbodiyan to waye lori ọrọ SARS.

Lara awọn tọwọ ba ni Ahmed Animashawun ati Alowonle Lawal, ẹni ọdun mejidinlọgbọn lawọn mejeeji, Adetunji Ṣeyi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Abdulganiyu Habeeb, ẹni ọgbọn ọdun, ati Taiwo Noah, toun jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun pere.

Kọmiṣanna Odumosu ni gbogbo awọn afurasi ọdaran wọnyi ni wọn maa foju bale-ẹjọ laipẹ ti iṣẹ iwadii ba ti pari lori ẹsun wọn.

Leave a Reply