Kọmiṣanna ọlọpaa Eko ka awọn eeyan kan mọ ile-ijo loru, lo ba ko gbogbo wọn

Faith Adebọla, Eko

Awọn eeyan to ju aadọta lọ, to jẹ pe ọdọkunrin ati ọdọbinrin lo pọ ju ninu wọn, lo ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Eko bayii, ile-ijo ni wọn wa, ti wọn tilẹkun mọri laajin oru, wọn lawọn n jaye ori awọn, ibẹ naa si lọwọ ti ba wọn.

Nnkan bii aago kan oru ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni Surulere, ni wọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ṣe sọ ninu atẹjade to fi sọwọ s’ALAROYE.

Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, funra ẹ, lo ko awọn ọmọ rẹ kan sẹyin, ni wọn ba lọọ ka awọn afurasi arufin naa mọ ibi ti wọn ti n ṣe faaji l’Ojule kejidinlogoji, Opopona Bọde Thomas, lagbegbe Surulere.

Ṣaaju lolobo kan ti ta ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn eeyan naa maa n wa sibẹ lalaalẹ, lai ka ofin ijọba ipinlẹ Eko to ka ile-ijo, ile-ọti ati agbo faaji leewọ, ati ofin ijọba apapọ to de rinrin kiri loru titi di aago mẹrin idaji, si.

Yatọ si ijo ati ọti amuyiraa, wọn lawọn kan maa n lọọ woran awọn to n jo ijo onihooho lapa kan ile ijo ọhun, awọn to si n lo oogun oloro, oogun amarale naa wa lẹgbẹẹ kan ni tiwọn.

Adejọbi ni ko sẹni to pa eewọ Korona mọ ninu wọn, wọn o bomu, wọn o si jinna sira, niṣe ni wọn n lọ mọ ara wọn bi wọn ṣe n jo ijo taka-sufee wọn lọ.

Yatọ sawọn ti wọn mu ni Surulere yii, wọn tun mu awọn mi-in loju ọna ti wọn n rin gberegbere kiri laago to yẹ kọmọluabi wa ninu ile ẹ, agbegbe Maryland ni wọn ti mu awọn yẹn, gbogbo wọn ni wọn rọ da sọkọ, wọn si ti fi wọn sahaamọ.

Ni bayii, ijọba ti fi agadagodo nla kan tilẹkun ile ijo naa pinpin.

Adejọbi ni kọmiṣanna ti paṣẹ pe ki wọn foju awọn afurasi alaigbọran wọnyi ba ile-ẹjọ, ki wọn le mọ idajọ to tọ si wọn, wọn yoo si ṣe bẹẹ topin ọsẹ ba ti kọja.

Leave a Reply