Kọmisanna Akeredolu mi-in tun ti darapọ mọ ẹgbẹ ZLP l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 Kọmisanna ileeṣẹ to n ri sọrọ epo rọbi nipinlẹ Ondo (OSOPADEC), Oloye Adeleke Adebisi Ilawọle, la gbọ pe o tun ti pada lẹyin ọga rẹ, Gomina Rotimi Akeredolu, pẹlu bo ṣe kọwe fipo silẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Ninu iwe to kọ, ọkunrin to wa lati ijọba ibilẹ Ilajẹ ọhun kọkọ dupẹ lọwọ gomina fun anfaani to fun un lati le ṣiṣẹ sin awọn eeyan ipinlẹ Ondo.

O ni oun lo asiko ọhun lati fi sọ fun Arakunrin pe oun ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii kọmisanna to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ilajẹ nileesẹ to n mojuto epo rọbi nipinlẹ Ondo.

Inu ẹgbẹ ZLP ni wọn ni Oloye yii gba lọ bo ṣe kuro ninu iṣejọba to n tukọ ipinlẹ Ondo lọwọ.

Bi lẹta yii ṣe tẹ Akeredolu lọwọ loun naa ti yara kede Ọgbẹni Gbenga Oluyide Mekuleyi gẹgẹ bii kọmisanna ajọ OSOPADEC tuntun.

Leave a Reply