Kọmisanna ọlọpaa Ondo bẹ awọn ọmọọsẹ rẹ ki wọn pada sẹnu iṣẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Amidu Salami, ti parọwa fawọn ọlọpaa to wa labẹ rẹ la ti pada ṣẹnu iṣẹ wọn lẹyin bii ọsẹ meji ti wọn ti jokoo pa si teṣan lai jade.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade to fi sita lorukọ kọmisanna ọhun. O rọ awọn agbofinro naa ki wọn gbagbe gbogbo iṣẹlẹ to waye lasiko iwọde SARS to kọja.

O ni o yẹ ki wọn ro ti ẹjẹ ti wọn jẹ la ti jẹ oloootọ ati olufaraji si pipeṣe aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu lai wo ti ipenija yoowu ti wọn le maa doju kọ.

Ọga ọlọpaa ọhun ni ohun to han sawọn ẹsọ alaabo wọnyi ni pe ki i ṣe awọn to n ṣe iwọde SARS ni wọn da rogbodiyan to waye naa silẹ, o ni awọn ọdaran kan ti iṣẹ takuntakun ti awọn n ṣe ba lẹru ni wọn fi iwọde naa boju la ti kọlu awọn ọlọpaa.

O ni o ṣee ṣe kawọn araalu tun maa foju ope ati ojo wo wọn bi wọn ṣe jokoo pa si teṣan ti wọn si kọ la ti ṣe ojuṣe wọn latari akọlu naa.

Salami ni ki i ṣe pe oun n paṣẹ fun wọn gẹgẹ bii ọga, o ni ẹbẹ loun n bẹ wọn ki wọn pada ṣenu iṣẹ wọn lẹyẹ-o-ṣọka ki iku awọn ẹgbẹ wọn ti wọn pa ma baa ja sasan.

Leave a Reply