Kọnstebu ọlọpaa kan ku lasiko tawọn adigunjale ya wọ ilu Iree

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe ni gbogbo ilu Iree, nijọba ibilẹ Boripẹ, nipinlẹ Ọṣun, n gbona janjan bayii latari ọṣẹ ti awọn adigunjale ti wọn ya wọnu ilu naa nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ṣe nibẹ.

Ni nnkan bii aago mẹrin ku diẹ la gbọ pe awọn atilaawi ti ẹnikẹni ko mọye wọn naa de, agọ ọlọpaa ni wọn si kọkọ doju kọ, wọn sọ fun awọn ọlọpaa pe eyi to ba fẹran ara rẹ ko parẹ loju-ẹsẹ.

Ṣugbọn a gbọ pe ọmọkunrin kọnstebu kan toun naa n ṣiṣẹ lagọọ ọlọpaa naa ko tete sa jade, idi niyẹn ti wọn fi doju ibọn kọ ọ, ti wọn si fọ ọ lori yannayanna.

Lẹyin eyi ni wọn doju kọ banki UBA ati Access Bank to wa lẹgbẹẹ araa wọn, wọn si fi bọmbu fọ ilẹkun ati ibi ti ẹrọ ipọwo POS wa.

Lọwọlọwọ bayii, a ko mọ iye owo ti wọn ko lọ lawọn ileefowopamọ naa, bẹẹ ni a ko ti i mọye awọn ti wọn fara pa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ọlọpaa ti lọ sibẹ lati mọ hulẹhulẹ nnkan to ṣẹlẹ gan-an.

Ṣugbọn awọn akẹkọọ fidii rẹ mulẹ fun ALAROYE pe ọna Ada ni awọn adigunjale naa gba sa lọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ. Oṣerekunrin ilẹ Ghana …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: