Kootu Agbaaye gba iwe ifiyajẹni ti Akintoye, Igboho kọ si wọn wọle

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ikọlu tawọn DSS to n ṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe sile Sunday Igboho lọjọ kin-in-ni, oṣu keje yii, ti de etiigbọ kootu ilẹ okeere to n gbọ ẹsun ọdaran bayii ni Rome, iyẹn International Criminal Court, wọn si ti lawọn yoo ṣiṣẹ le e lori bo ṣe yẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtala, oṣu keje yii, ni kootu naa sọ ọ di mimọ pe awọn ri lẹta ifisun ti Sunday Igboho ati Ọjọgbọn Banji Akintoye pẹlu awọn mọkandinlaaadọta ti wọn n beere idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba fi ṣọwọ si ọfiisi awọn, eyi to jẹ gbogbo wọn ni fọwọ si i.

Lẹta ti awọn Igboho kọ naa ni wọn fi pe Aarẹ Muhammadu Buhari lẹjọ, pẹlu Abubakar Malami to jẹ minisita eto idajọ ni Naijiria. Bakan naa ni wọn pe ọga awọn ṣọja tẹlẹ lorilẹ-ede yii,Tukur Buratai, lẹjọ pẹlu, awọn ọga ọlọpaa pata tẹlẹ; Ibrahim Idris ati Muhammed Adamu.

Ninu lẹta naa ni awọn to n beere idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba ti fẹsun ipaniyan kan awọn olori eto aabo nilẹ yii, wọn ni wọn huwa ifiyajẹni fun iran Yoruba ti i ṣe Ekiti, Ọyọ, Ọṣun, Kwara, Ondo, Ogun, Eko titi kan awọn eeyan Okun, ni Kogi.

Nigba tawọn kootu ilẹ okeere naa gba lẹta yii, wọn da esi pada pe o ti de ọdọ awọn o, awọn yoo si da esi pada nipa kikọwe sawọn olufisun yii, awọn yoo ba wọn sọrọ bi iwadii awọn ba ṣe n lọ ni pẹrẹwu.

Oju ewe mẹtadinlọgbọn (27 pages) ni lẹta tawọn ajijagbara ‘Yoruba Nation’ kọ naa ni, wọn si ṣalaye bawọn DSS ṣe wọle Igboho loruganjọ, ti wọn paayan, ti wọn tun ba dukia olowo iyebiye jẹ, ati bi wọn ṣe da aibalẹ ọkan ti ko ni i tan silẹ lara awọn ti wọn ba ninu ile naa gbogbo.

Ṣugbọn yatọ si alaye ohun to ṣẹlẹ yii,awọn ajijagbara yii lawọn mọ ohun tawọn fẹ, iyẹn naa ni Maxwell Adelẹyẹ, Alukoro ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ṣe sọ ninu atẹjade wọn pe iran Yoruba ni lati tẹsiwaju bayii nipa fifi ẹnu ko si igbesẹ kan. Igbesẹ to jẹ idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba lo da le lori.

Wọn ni bii igba teeyan fẹẹ dibo ni yoo ri, ti awọn to fẹ idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba yoo to si apa kan, awọn ti wọn ko fẹ yoo to si apa keji, awọn yoo si wo onka ibi ti kinni ọhun ba fi si ju, iyẹn lawọn yoo fi mọ ohun to wa lọkan awọn ọmọ ku-ootu- oo-jiire.

Ohun ti awọn ajijagbara yii n beere gan-an ati idi ti wọn fi kọ lẹta ifisun ni pe wọn ni titẹ ẹtọ ọmọniyan loju n ṣẹlẹ ni Naijiria lọwọlọwọ, paapaa fun awọn ọmọ Yoruba. Wọn ni awọn Fulani n jẹ gaba le Yoruba lori nilẹ wa, ki ile-ẹjọ ilẹ okeere (Ilu Rome) ti Naijiria jẹ alafisun ẹ bẹrẹ iwadii wọn lori ẹ, ki wọn ri i funra wọn, ki wọn si bẹrẹ igbesẹ lati fi awọn arufin jofin.

Yatọ si Igboho ati Ọjọgbọn Akintoye, diẹ ninu awọn ti wọn tun fọwọ si lẹta yii ni: Imaamu Yoruba n’Ilọrin; Sheikh Raheem Aduranigba, Olori obinrin Oodua Agbaye; Oloye Simisade Kuku, Akọwe gbogbogboo fẹgbẹẹ Ilana Ọmọ Oodua; George Akinọla ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa lo si jẹ pe yatọ si Buhari, Malami atawọn ọga ọlọpaa meji tẹlẹ ti wọn fẹsun kan, wọn tun darukọ  Ọga kọstọọmu, Hammid Alli, Ọga ọlọpaa tuntun; Alkali Baba, ọga ṣọja tuntun; Farouk Yahaya ati bẹẹ bẹẹ lọ gẹgẹ bii ẹni to gbe sẹyin awọn DSS, ti wọn wọle waa daamu gbogbo Yoruba nipa wiwọle Igboho loru, bẹẹ ọkunrin naa ko huwa aitọ, ẹtọ rẹ lo n beere fun iran rẹ, eyi ti ki i ṣe ẹṣẹ labẹ ofin.

Leave a Reply