Kootu da awọn mẹta to yinbọn paayan lasiko idibo l’Ekiti pada sọgba ẹwọn

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu keje yii, nile-ẹjọ Majisireeti kan to wa l’Ado-Ekiti, paṣẹ pe ki wọn da awọn eeyan mẹta kan ti wọn ni wọn yinbọn paayan lasiko ibo to waye gbẹyin nipinlẹ Ekiti pada sọgba ẹwọn.

Awọn mẹta naa ni: Adeniji Oluṣọla; ẹni ọdun mejilelogoji (42), Paul Fọlọrunṣọ; ẹni ọdun marundinlọgọta (55) ati Adebayọ Ṣẹrifat to jẹ ẹni ogoji ọdun (40).

Ẹsun ti kootu fi kan wọn ni pe wọn yinbọn pa eeyan mẹta lasiko idibo sile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, eyi to waye logunjọ, oṣu kẹta, ọdun yii.

Omu-Oke, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti, ni wọn ti huwa naa gẹgẹ bi kootu ṣe wi. Awọn ti wọn pa naa ni Babatunde Adelẹyẹ, Bọla Adebisi ati sajẹnti obinrin torukọ rẹ n jẹ Bukọla Ọlawọye.

Yatọ sawọn to doloogbe yii, wọn ni awọn afurasi naa tun ṣe awọn ọlọpaa mẹta mi-in leṣe, orukọ wọn ni Akanle Oluwadare, Tosin Adeniyi, ati Ọmọlọla Emmanuel.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ, Amofin Busuyi Ayọrinde, gbiyanju lati jẹ ki kootu fun awọn eeyan rẹ ni beeli, ṣugbọn Adajọ Abdulhamid Lawal ko gba ipẹ rẹ. O paṣẹ pe ki wọn da awọn olujẹjọ pada sọgba ẹwọn, o si sun igbẹjọ siwaju.

Leave a Reply