Kootu fẹẹ pe Yọmi Fabiyi lẹjọ nitori sinima ‘Ọkọ Iyabọ’

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹka ti wọn ti n ri si ipẹjọ lawọn kootu Eko (Directorate of Public Prosecution), DPP, ti ṣetan bayii lati pe oṣere tiata nni, Yọmi Fabiyi, lẹjọ, nitori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ to gbe jade sori ayelujara.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ni DPP sọ ọ di mimọ pe Yọmi lufin kootu, pẹlu bo ṣe lọọ fi ẹjọ to wa ni kootu ṣe fiimu, to si dohun ti gbogbo aye n ri.

Yatọ si eyi, wọn ni iwa to lodi sofin ni, pe keeyan lo orukọ awọn eeyan tọrọ kan ninu ẹjọ kan, ki tọhun waa fi ṣe fiimu lai yi ohunkohun pada nibẹ.

Ọga agba lọdọ awọn DPP, Ọlayinka Adeyẹmi, lo sọ eyi di mimọ nigba to n ṣalaye lori fiimu  Ọkọ Iyabọ ti Yọmi ṣe yii.

O ni igbẹjọ kootu lori ẹsun Baba Ijẹṣa ti wọn lo ba ọmọde sun ni Yọmi sọ di ere lasan, bẹẹ lẹyin ti kootu gbọ ẹjọ naa lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2021, ni Yọmi gbe fiimu naa jade.

Ọga DPP naa sọ pe pẹlu bi kootu ṣe kilọ to lọjọ naa pe keesi yii ṣi n lọ lọwọ, awọn nnkan kan ko si gbọdọ lu sita nipa ẹ, ki ẹnikẹni ma ṣe gbe e jade, o ni sibẹ, Yọmi Fabiyi kọti ikun si aṣẹ ile-ẹjọ, o gbe ‘Ọkọ Iyabọ’ jade pẹlu orukọ awọn to ṣẹlẹ si.

 Koda, orukọ awọn ẹlẹrii paapaa ko yipada ninu fiimu naa gẹgẹ bi Ọlayinka ṣe wi, o ni gbogbo ẹ ni Yọmi lo ninu fiimu, to n fi ohun to ṣẹlẹ sawọn ẹni ẹlẹni ṣe ere lasan. Fun idi eyi, o ni ọkunrin naa lẹjọ i jẹ l’Ekoo, yoo si foju ba kootu dandan.

jugbọn Yọmi Fabiyi funra ẹ ti fi ohun silẹ ko too gba ilu oyinbo to wa bayii lọ. Ọkunrin naa sọ pe oun ko lufin kankan, ero ọkan oun loun fi ṣere, eyi ti ẹnikẹni to ba jẹ onkọtan le ṣe labẹ ofin.

Lọọya rẹ naa gbe e lẹsẹ, Amofin Dada Awoṣika, o ni ki kootu too bẹrẹ si i gbọ ẹjọ yii ni Yọmi ti ṣe  fiimu rẹ .

Lọọya yii sọ pe ohun ti fiimu naa da le lori ni ariyanjiyan laarin oṣere meji, iyẹn Yọmi Fabiyi ati Iyabọ Ojo. O ni kaluku wọn lo ni igun to n ṣatilẹyin fun, ero wọn ko papọ, ohun to ṣẹlẹ gan-an niyẹn.

Ṣugbọn ero ọkan awọn eeyan to gbọ ohun ti DPP fẹẹ ṣe fun Yọmi Fabiyi ko ri bakan naa, awọn kan n sọ pe ijọba wulẹ fẹẹ nawo ara Eko lori iranu ni. Wọn ni ki lo kan ijọba Eko pẹlu awọn onitiata, ti wọn yoo fi maa fowo ilu ṣe ẹjọ fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ kan. 

Awọn mi-in sọ pe Yọmi ko jẹbi rara pẹlu orukọ to lo ninu fiimu rẹ, wọn ni ṣe Iyabọ Ojo lo pe e ni, ṣebi ‘Ọkọ Iyabọ’ lasan ni, aimọye Iyabọ kaakiri agbaye. Wọn ni ọpọlọ ni Fabiyi fi ṣe fiimu rẹ, ko si yẹ ki ijọba mu un nitori iyẹn.

Ṣugbọn awọn to foju ofin wo o sọ pe bi DPP ṣe fẹẹ pe e lẹjọ yẹn lo daa. Wọn ni o lodi sofin patapata lati fi ẹjọ to wa ni kootu ṣere, o lodi sofin lati lo orukọ awọn tọrọ kan, ko si boju mu lati fi iru rẹ pawo rara.

Yọmi Fabiyi ṣi wa niluu oyinbo lasiko ti a n kọ iroyin yii, bi asiko igbẹjọ rẹ ba to ni Naijiria yii, o ṣee ṣe ko wale waa jẹjọ ẹsun tijọba fi kan an.

Leave a Reply