Kootu ju iyawo to n wo foonu ọkọ ẹ lai gbaṣẹ sẹwọn oṣu mẹta

Fun bo ṣe maa n ji foonu ọkọ ẹ wo lalaalẹ nigba ti ọkunrin naa ba sun tan lai gba aṣẹ lọwọ rẹ, ti yoo maa ka awọn atẹjiṣẹ to wa nibẹ, ile-ẹjọ ti sọ obinrin kan ti wọn forukọ bo laṣiiri sẹwọn oṣu mẹta lorilẹ-ede Dubai.

Ọkọ obinrin naa lo pe e lẹjọ lẹyin ti aṣiri iyawo yii tu si i lọwọ. Niṣe lọkọ ṣalaye fun kootu pe boun ba ti sun tan, iyawo oun yoo si ki foonu oun mọlẹ, yoo maa ka awọn atẹjiṣẹ to wa nibẹ, yoo maa wo fọto, yoo si tun maa ji data oun sori foonu tiẹ.

Ki i ṣe pe obinrin naa n ka awọn atẹjiṣẹ naa lasan o, ọkọ sọ pe yoo tun taari gbogbo ẹ sori foonu tiẹ, yoo waa maa ka a nigba toun ko ba si nibẹ. Bẹẹ, ki i gba aṣẹ lọwọ oun to fi n huwa yii, eyi to lodi sofin United Arab Emirate, Dubai, ti wọn n gbe.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ ni kootu naa to wa ni Ras Al Khaimah, iyawo sọ pe oun fura sọkọ oun pe o n yan ale ni. O ni nitori ẹ loun ṣe n dọgbọn wo foonu ẹ to ba sun tan, nitori oun ko fẹẹ mu un laaabọ, oun fẹẹ ri okodoro ọrọ naa ni.

Ṣugbọn kootu ran an leti pe labẹ bo ṣe wu ko ri, ofin ti wa pe lọkọ-laya ko gbọdọ wo foonu ara wọn lai gba aṣẹ. Fun eyi to ṣe yii, wọn ni iyawo naa ti lufin ilu awọn, n ni wọn ba ran an lewọn oṣu mẹta.

Leave a Reply