Kootu kọ lati gba beeli aṣofin ilẹ wa atiyawo ẹ ti wọn mu niluu oyinbo

Faith Adebọla

Ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun yii, ni ile-ẹjọ kan to n gbọ ẹsun ti wọn fi kan ọkan ninu awọn aṣofin ilẹ wa, Ike Ekweremadu, ẹni ọgọta ọdun, ati iyawo rẹ, Beatrice Nwanneka Ekweremadu, ẹni ọdun marundinlọgọta, niluu London.
Ẹsun ti awọn ọlọpaa orileede United Kingdom to fidi ẹ mulẹ pe igbakeji olori awọn aṣofin ilẹ wa tẹlẹri naa ti wa lakolo awọn, fi kan wọn ni pe wọn mu ọmọ kan wa sorileede UK lati yọ ẹya ara ẹ ta.
Atẹjade kan latọdọ awọn ọlọpaa Metropolitan Police, ti United Kingdọm, sọ pe owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa yii, ni wọn mu awọn afurasi ọdaran mejeeji, ti wọn si kawọn pọnyin rojọ nile-ẹjọ Uxbridge Magistrates, laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, kan naa.
Lara ẹsun ti wọn fi kan tọkọ-taya naa ni pe wọn gbimọ-pọ lati ṣeto irinajo fun ọmọkunrin kan ti wọn fẹẹ lo awọn ẹya ara ẹ kan, lati fi ṣowo ẹya ara tita.
Awọn ọlọpaa naa lawọn ti daabo bo ọmọ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ rẹ, wọn ko si sọ ọjọ-ori ẹ.
Scotland Yard, to sọ ọrọ yii di mimọ sọ pe latinu oṣu Karun-un, ọdun yii, lolobo ti ta awọn agbofinro nipa erongba ati eto lati mu ọmọ naa wa, awọn si ti ṣiṣẹ iwadii, eyi to fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi ọdaran mejeeji yii mọ nipa ọrọ naa.
Wọn ni ọmọ ọdun mẹẹẹdogun ti ko ni ibi kan to n gbe niluu Eko ni awọn tọkọ-taya naa mu wa si UK.
Wọn ni iwa naa ta ko ofin orileede UK lori fifi ọmọde ṣowo ẹru, ati lilo ẹya ara eeyan lọna aitọ.
Ṣugbọn ohun mi-in ti ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe ara ọmọbinrin Ekweremadu kan ti orukọ rẹ n jẹ Sonia ni ko ya, o ni arun kindinrin. Kindinrin rẹ yii ni wọn fẹẹ paarọ ti wọn fi n wa ẹni ti wọn le yọ ọkan ninu tiẹ si ti ọmọbinrin yii.
Eyi lo fa a ti wọn fi mu ọmọkunrin ti orukọ rẹ n jẹ Ukpo Nwanimi David lọ si ilu oyinbo fun iṣẹ abẹ lati yọ kindinrin rẹ.
Ninu lẹta kan ti akọroyin wa ri lori ayelujara lo ti han pe Ekeremadu kọwe si ileeṣẹ to n ṣoju ilu oyinbo nilẹ wa nigba to fẹẹ gba iwe irinna fun ọmọ rẹ ati ọmọkunrin yii, to si kọ ọ sibẹ pe ọmọkunrin naa fẹẹ fun ọmọ oun ni kindinrin ni wọn ṣe fẹẹ tori rẹ mu un lọ siluu oyinbo.
Ju gbogbo ẹ lọ, ile-ẹjọ ilu oyinbo naa ko gba beeli tọkọ-tiyawo yii. Ọjọ keje, oṣu Keje, ni wọn sun igbẹjọ mi-in si.

Leave a Reply