Kootu sọ pasitọ sẹwọn gbere nitori ẹsun ipaniyan, ọjọ kẹta lo dagbere faye

Iyalẹnu ni iku pasitọ obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Edna Lovely Worleru ṣi n jẹ fawọn eeyan titi dasiko yii, nitori ọjọ kẹta ti ile-ẹjọ ju u sẹwọn gbere lori ẹsun ipaniyan loun naa ku lojiji ni Pọtakọọtu, nipinlẹ Rivers.

Ọjọ kẹrindindinlogun, oṣu kẹsan-an yii, ni ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers paṣẹ pe ki obinrin ti ṣọọṣi rẹ wa lagbegbe Rumuche, nijọba ibilẹ Emohua, nipinlẹ Rivers, naa lọọ lo iyoku aye rẹ lẹwọn, nitori iku pasitọ ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Israel Georgewill, eyi ti wọn ni iya yii mọ nipa ẹ.

Gẹgẹ bi alaye kootu naa latẹnu Agbefọba Chidi Ekeh, o ni obinrin kan ti wọn n pe ni Onyema Bright lo ni oun nifẹẹ si pasitọ Israel, oun fẹ ko maa fẹ oun, ṣugbọn pasitọ naa ko wo ọdọ oun rara. Nigba ti ohun ti obinrin yii n fẹ ko bọ si i lo lọọ ba iya adura, Edna Worleru, pe ko ba oun ṣoogun ifẹ si pasitọ naa, ko le ṣe toun.

Oogun ifẹ naa ni Edna ṣe fun Bright Onyema, niyẹn ba lọọ lo o fun pasitọ to wu u lati fẹ. Afi bi oogun ifẹ naa ṣe di oogun iku, nitori bi Bright ṣe lo o fun pasitọ bayii, ọkunrin naa jade laye ni.

Ohun to gbe Bright ati Pasitọ Edna to ṣoogun fun un de kootu ree lọdun 2012 ti iṣẹlẹ yii waye. Ṣugbọn lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an yii, ile-ẹjọ dajọ naa, adajọ si paṣẹ pe ki Bright Onyema to n wa oogun ifẹ kiri, ati Edna Worleru to ṣe e fun un ti wọn fi pa Pasitọ Israel Georgewill lọọ lo igbesi aye wọn yooku lẹwọn.

Afi bo ṣe di ọjọ kẹta lẹyin idajọ naa, eyi ti i ṣe ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹsan-an, ti pasitọ Edna Worleru ta teru nipaa, wọn ni aisan diẹ bayii lo ṣe e to fi tẹri-gbasọ.

Agbenusọ ijọba lori ẹjọ naa waa sọ pe oku ijọba loku Edna, nitori ọdaran ni titi to fi ku. O ni o ṣee ṣe kawọn ma gbe oku naa fawọn ẹbi ẹ, ko gba mọṣuari debi ti wọn yoo ti i so ẹwọn mọ saaree rẹ gẹgẹ bii arufin to ku.

Leave a Reply