Korona burẹkẹ l’Ekoo, eeyan mẹfa ku, aadọrin le lẹẹẹdẹgbẹta tun ko o

Faith Adebọla,

Pẹlu bijọba ṣe n ke tantan ti wọn si n sapa lori itankalẹ arun aṣekupani Korona yii, niṣe ni kinni naa n pọ si i nipinlẹ Eko. Lọjọ kan ṣoṣo pere, eeyan mẹfa lo dagbere faye, ti aadọrin le lẹẹẹdẹgbẹta (570) mi-in si ṣẹṣẹ lugbadi ẹ.

Ajọ to n gbogun ti itankanlẹ arun yii nilẹ wa, NCDC, lo kede ọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ninu iroyin ojoojumọ ti wọn n ṣe lati sọ ibi ti nnkan de duro lori arun buruku ọhun nilẹ wa.

Iroyin naa lo sọ pe lọjọ kan ṣoṣo, iyẹn ọjọ Tọsidee to gbẹyin ninu ọdun 2020, arun ọhun burẹkẹ gidi nipinlẹ Eko, iye eeyan to ku atawọn to ṣẹṣẹ lugbadi rẹ yii lo ti i pọ ju lọ latigba ti itankalẹ arun naa ti gberi si i lẹẹkeji, eyi ti wọn n pe ni Korona Keji (CORONA 2).

Yatọ siyẹn, ipinlẹ Eko nikan lo ko ohun to ju idaji lọ ninu aropọ gbogbo awọn to ṣẹṣẹ lugbadi arun ọhun lapaapọ orileede wa, tori ẹgbẹrun kan ati mọkanlelọgbọn awọn eeyan larun naa mu lọjọ kọkanlegbọn oṣu kejila yii, gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Ni bayii, latigba ti arun Korona ti bẹ silẹ nipinlẹ Eko, eeyan ojilerugba ati meje (247) lo ti doloogbe lairoti, ẹgbẹrun lọna ọgbọn ati mejidinlaadọwaa (30,188) lo ti lugbadi ẹ, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn ati ọkanlelogoje (26,141) lawọn to ti gbadun, nigba tawọn to ku ṣi n gba itọju lọwọ lawọn ibudo iyasọtọ ati ileewosan kaakiri ipinlẹ ọhun.

Leave a Reply