Korona: Ijọba ni kawọn ileewe girama ati alakọọbẹrẹ ṣi wa ni titi nipinlẹ Eko

Faith  Adebọla, Lagos

Eto ẹkọ fun saa tuntun to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu ki-in-ni, ọdun 2021 yii, ko ni i waye mọ, latari bijọba ipinlẹ Eko ṣe paṣẹ pe kawọn ileewe pamari ati sẹkọndiri kaakiri ipinlẹ naa ṣi tilẹkun wọn na.

Atẹjade kan lati ọfiisi Alukoro fun ẹka eto ẹkọ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Kayọde Abayọmi, sọ lọjọ Aiku, Sannde yii, pe ijọba ti wọgi le iwọle awọn akẹkọọ lawọn ile-ẹkọ naa, ati ti aladaani ati tijọba.

O ni igbesẹ yii ko ṣẹyin bijọba ṣe n kiyesi arankanlẹ arun Korona to tun fẹẹ burẹkẹ lẹẹkeji nipinlẹ Eko, ati bi ọrọ aabo awọn ogo wẹẹrẹ ṣe jẹ ijọba logun gidi.

Atẹjade naa sọ pe ko ti i sẹni to mọ igba ti saa tuntun yoo bẹrẹ bayii, o ni kawọn obi ati olukọ ṣi lọọ mu suuru, titi tijọba yoo fi kede ọjọ iwọle fun saa ẹkọ tuntun laipẹ.

Wọn waa gba awọn obi niyanju lati ri i pe wọn tubọ daabo bo awọn ọmọ wọn lọwọ arun aṣekupani ọhun, nipa riri i daju pe awọn ọmọ naa n lo ibomu, wọn n fomi ati ọṣẹ fọ ọwọ wọn deede, wọn si n lo kẹmika apakokoro, sanitaisa, to yẹ nigba gbogbo.

Leave a Reply