Korona mu oṣiṣẹ DSTV n’Ibadan, wọn ba ni kawọn onibaara wọn lọọ fira wọn pamọ sile

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oṣiṣẹ ileeṣẹ Multichoice, iyẹn ileeṣẹ to ni ẹrọ amohunmaworan alatagba ti wọn n pe ni DSTV n’Ibadan ti lugbadi arun Korona.

Eyi lo mu ki awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọhun sọ fawọn onibaara wọn to ti ni nnkan kan tabi omi-in i ṣe lọfiisi wọn lẹnu ọjọ mẹta yii lati lọọ fi ara pamọ sile wọn fun asiko diẹ naa.

Ninu atẹjade ti Abilekọ Caroline Oghuma fi sita lorukọ igbimọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ DSTV nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ana, lo ti sọ ojú abẹ níkòó pe ọkan ninu awọn oṣiṣẹ awọn ti ṣayẹwo Korona, abajade ayẹwo ọhun si fi han pe kokoro arun naa ti wa ninu ẹjẹ rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Laipẹ yii la ri i pe ọkan ninu awọn oṣiṣẹ wa, ni ẹka ọfiisi wa kẹrinla to wa l’Onireke, n’Ibadan, ti ni kokoro arun Korona lara. O si ti n gba itọju nileewosan lọwọ bayii.

“Gbogbo ẹyin tẹ ẹ ba wa si ẹka ọfiisi wa yii laarin ọsẹ meji sẹyin, bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, si ọjọ kọkanla, oṣu keje ọdun 2020 yii, o ṣee ṣe kẹ ẹ ti ni ifarakinra pẹlu ẹni to ni kokoro Korona lara yii. Nitori naa, a rọ yin lati sé ara yin mọ́lé fun asiko diẹ nitori.”

Leave a Reply