‘Korona ni ko ti jẹ ka ṣafikun si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ataabọ ti oṣiṣẹ to kere ju lọ nipinlẹ Ọyọ n gba’

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ipinlẹ Eko, ijọba ipinlẹ Ọyọ lo tun n sanwo daadaa ju lọ fawọn oṣiṣẹ, ifasẹyin ti ajakalẹ arun Korona mu ba eto ọrọ aje nilẹ yii ati kaakiri agbaye ni ko jẹ ki wọn ti fi kun owo naa.

 

Eyi jẹ yọ ninu ọrọ ti Ọgbẹni Bayọ Titilọla Sodo ti i ṣe oludamọran fun Gomina Ṣeyi Makinde lori ọrọ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa sọ fawọn oniroyin lasiko ti ẹgbẹ awọn aṣojukọroyin (Correspondents’ Chapel) ninu ẹgbẹ NUJ ipinlẹ Ọyọ gba a lalejo l’Ọjọruu, Wẹsidee.

Ọgbẹni Sodo sọ pe lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin lawọn oṣiṣẹ atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọyọ ti n koju iṣoro airowogba lasiko, ati pe ọpọ igba ni wọn ki i rowo wọn gba pe, to jẹ aabọ owo ni wọn maa n ri gba, tabi ki awọn oṣiṣẹ-fẹyinti  gba owo lẹẹkan ṣoṣo laarin oṣu mẹta.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọyọ ko niṣoro rara lori ọrọ ilana owo-oṣu tuntun ti ijọba apapọ gbe kalẹ nitori a ti n sanwo yẹn fawọn oṣiṣẹ wa ni tiwa. Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ataabọ (N30,500) lowo ti oṣiṣẹ to kere ju lọ nipinlẹ Ọyọ n gba. A ba ti ṣafikun ẹ gan-an bi ki i baa ṣe ọrọ Korona to ba eto ọrọ aje jẹ.

“Bii ẹgbẹrun mọkanlelọgọrun-un (101,000) oṣiṣẹ la ni ni ipinlẹ Ọyọ. Ileewe girama ta a ni nipinlẹ yii le lẹgbẹta. Ẹ waa wo iye oṣiṣẹ to maa wa nileewe girama nikan.”

Nigba to n sọrọ lori ọna ti ijọba n gba gbogun ti iwa ibajẹ laarin awọn oṣiṣẹ, oludamọran gomina yii sọ pe “Awọn kan n gbowo lati ba awọn oṣiṣẹ-fẹyinti fiili fọọmu, ẹni to ba wa ṣe e funra rẹ, wọn le fi faili rẹ ṣawati.

“A le awọn kan danu lẹnu iṣẹ lọsẹ meji sẹyin lori ọrọ riba gbigba ki wọn too le fun awọn oṣiṣẹ-fẹyinti lowo-oṣu.

Ko too di pe Gonina Ṣeyi Makinde gori aleefa, iṣoro to n koju awọn oṣiṣẹ ni pe wọn kì í rí owó-oṣu wọn gba pe, bẹẹ lawọn oṣiṣẹ-fẹyinti le ma ri owo gba ju ẹẹkan lọ laarin oṣu mẹta. Ṣugbọn nnkan ti yatọ lasiko iṣejọba Makinde, owo to ti fi sanwo oṣu ati owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti laarin ọdun meji to ṣẹṣẹ lo nipo yii ti to ilopọ marun-un iye owo ti ijọba mi-in to ti kọja na fun awọn beeyan yii laarin ọdun mẹrin ti won fi ṣejọba lọ.

Ọgbẹni Sodo, ẹni to ti fi ọpọlọpọ ọdun wa lara awọn adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ (NLC) nipinlẹ Ọyọ, ko ṣai bu ẹnu atẹ lu lile ti gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, le ọpọlọpọ oṣiṣẹ ijọba danu nipinlẹ rẹ, o ni igbesẹ to lodi sofin patapata gbaa ni gomina naa hu.

 

Leave a Reply