Korona: Ọjọgbọn Ibrahim ṣatilẹyin fun ẹkọ ayelujara

Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ọgba-agba Fasiti Al-Hikmah niluu Ilọrin tẹlẹ, Ọjọgbọn Mohammed Taofeek Ibrahim, ti rọ ijọba apapọ lati ma ṣi awọn ileewe bayii, ṣugbọn kawọn akẹkọọ maa kọ ẹkọ wọn lori ẹrọ ayelujara.

Ibrahim to kawe gboye ninu eto ilera araalu (Public Health) sọrọ naa lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin.

Ọjọgbọn to ti figba kan ṣiṣẹ pẹlu ajọ to n mojuto eto ilera lagbaaye, WHO, ni ẹmi awọn akẹkọọ atawọn olukọ ṣe pataki, fun idi eyi, ijọba gbọdọ ri i pe arun Korona din ku ki wọn too pada sileewe.

O ṣalaye pe arun naa ko figba kan da iṣẹ tabi ẹkọ duro nileewe Al-Hikmah nitori pe ṣaaju ki kinni ọhun too dohun to n tan kaakiri lawọn ti n kọ awọn akẹkọọ awọn lati ori ẹrọ ayẹlujara.

Nigba to n sọrọ lori ipa to ti ko laarin ọdun 2015 si asiko to fipo silẹ gẹgẹ bii ọga-agba fasiti naa, o ni Ọlọrun ti ran oun lọwọ lati mu igbega ba ileewe ọhun ju boun ṣe ba a.

O dupẹ lọwọ oludasilẹ Fasiti Al-Hikmah, Jagunmolu tilẹ Igbomina to tun jẹ Arogundade tiluu Eko, Alhaji Abdur-Raheem Ọladimeji, fun anfaani lati ṣe akoso ileewe giga naa.

Leave a Reply