Korona pa alaga ẹgbẹ awọn dokita tẹlẹ l’Ondo

Alaga ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo tẹlẹ, Dokita Michael Adeyẹri, ti dagbere faye lẹyin to lugbadi arun Koronafairọọsi.

Oni, Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe Adeyẹri ki aye pe o digbooṣe nileewosan lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ itọju rẹ.

Bi iroyin kan ṣe ni ọsibitu toun funra ẹ da silẹ lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ, lo ku si niroyin mi-in ni ileewosan ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ lo ti pada dagbere faye.

Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo, Dokita Wale Oke, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii lawọn olubanikẹdun n ya lọ si ọsibitu rẹ, iyẹn Shekinah Hospital, ni Alagbaka.

Leave a Reply