Korona pa kọmiṣanna eto ẹkọ tẹlẹ nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta yii, ni kọmiṣanna tẹlẹ feto ẹkọ nigba iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Amofin John Ṣẹgun Odubẹla, dagbere faye. Aisan Korona lo pa a lọsibitu kan niluu Eko, ẹni ọdun marunlelaaadọta (55) ni.

 

ALAROYE gbọ pe o ti to ọsẹ meji ti Odubẹla ti wa lọsibitu kan l’Ekoo, ti wọn n tọju rẹ. Ṣugbọn nigba to di aarọ kutu ọjọ Iṣẹgun yii, ọlọjọ de.

Ọmọ ilu Ikẹnnẹ Rẹmọ ni Oloogbe Odubẹla, ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 2017 lo gba oye amofin agba ilẹ Naijiria ti i ṣe SAN.

Saa akọkọ Sẹnetọ Amosun ni ọkunrin yii ṣe kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply