Korona ti tan ka ijọba ibilẹ mẹẹẹdogun, eeyan mẹrindinlogoji lo tun ti mu ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Eeyan mẹrindinlogoji lo tun ko arun Koronafairọọsi l’ọgbọn, oṣu kejila, ọdun yii, nipinlẹ Kwara, eyi si ti mu ki kinni ọhun tan ka ijọba ibilẹ mẹẹẹdogun ninu mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa.

Iye awọn to ni i ti wọn n gba itọju lọwọ ti wọ igba le mẹrin gẹgẹ bi atẹjade ti igbimọ to n mojuto Covid-19 ṣe sọ.

Atẹjade naa fi han pe ijọba ibilẹ Ilọrin South lo lewaju, ko too kan Ilọrin West, ati Ila-Oorun Ilọrin (East).

Ijọba ibilẹ Ekiti lo ni eyi to kere ju, eeyan meji pere niwadii fi han pe o ko arun naa bayii, bo tilẹ jẹ pe ayẹwo ṣi n tẹsiwaju lati mọ ibi tawọn eeyan ọhun ti tan arun naa de.

Esi ayẹwo ọgọfa ati mẹrinla ni wọn ṣi n reti bayii, lẹyin tiyẹn ba jade ni wọn yoo too mọ iye awọn to ṣi ni arun naa.

Leave a Reply