Korona tun pa adajọ agba ilẹ wa tẹlẹ, Abdullahi Ibrahim

Adajọ agba ati minisita fun eto idajọ ilẹ wa nigba kan, Alaaji Abdullahi Ibrahim, ti dagbere faye.

Ọsan ọjọ Aiku, Sannde yii, lọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kogi naa doloogbe ni ibudo iyasọtọ fawọn to n gba itọju lori arun Korona, l’Abuja.

Abdullahi lo ṣe minisita feto idajọ lasiko iṣejọba Ọgagun-fẹyinti Abdulsalami Abubakar, o si wa nipo naa titi ti wọn fi gbejọba fun Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ gẹgẹ bii aarẹ lọdun 1999.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ yan an sipo minisita feto irinna ọkọ lasiko ijọba ologun ti Ọgagun-fẹyinti Muhammadu Buhari ṣe, lọdun 1984.

Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) ṣe wi, ninu ọsẹ to kọja yii la gbọ pe wọn gbe ọkunrin naa lọ sibudo awọn to lugbadi arun Korona, ni Abuja, oju ẹsẹ ni wọn si ti n fun un ni itọju to yẹ.

Wọn ni owurọ ọjọ Aiku, Sannde yii, ni kinni naa tun yiwọ, ti wọn ko si rọgbọn da si i mọ, ti baba naa fi doloogbe.

Leave a Reply