Korona tun pa Alaga Ijọba Ibilẹ Idagbasoke Onigbongbo

Ọkan ninu awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Francis Babatunde Oke, to jẹ alaga Ijọba Ibilẹ Onigbongbo ti ku o. Arun aṣekunpani to gbode nni, Koronafairọọsi, ni wọn lo mu ẹmi ọkunrin naa lọ ni Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe pe ọkunrin to n lo saa keji lọ nipo alaga naa ti n saisan fun ọsẹ diẹ, to si da bii ẹni pe o ti n gbadun diẹdiẹ. Ẹẹkan naa ni wọn ni aisan ọhun tun mi pada, ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan kan ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja. Ọsibitu ọhun lo pada ku si ni fẹẹrẹ Ọjọbọ, Wẹsidee ọsẹ yii.

A gbọ pe ipa takuntakun ni ọkunrin naa ko lati la awọn eeyan ijọba ibilẹ rẹ lọyẹ nipa arun Korona yii. Awọn kan ni o ṣee ṣe ko jẹ asiko to n lọ kaakiri yii lo ti ko kinni ọhun ti ko mọ, eyi to pada pa a yii.

Ojiji ni iku ọkunrin naa ja lu awọn ololufẹ rẹ, paapaa awọn ti ko mọ pe ọkunrin naa wa nileewosan.

Awọn ọrẹ atawọn alatilẹyin rẹ nidii oṣelu ti n rọ lọ sile rẹ lati ba awọn ẹbi rẹ kẹdun.

Leave a Reply