Korona tun pa elomi-in l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede pe arun Koronafairọọsi ti pa ẹni kan nipinlẹ naa lẹyin bii ọsẹ kan ti iru ẹ waye gbẹyin.

Oloogbe naa la gbọ pe arun naa wọ lara kọja agbara awọn oniṣegun, oun si ni ẹni kẹrin tiru ẹ ṣelẹ si nipinlẹ naa.

Bakan naa ni Ekiti tun ni eeyan mẹwaa mi-in to ko arun naa, eyi tọ sọ iye awọn to n gba itọju lọwọ di mejilelọgọrun-un (102).

Gẹgẹ bii akọsilẹ, gbogbo awọn to ti ko arun Korona l’Ekiti jẹ igba-le-mẹrindinlogun (216).

Leave a Reply