Korona tun paayan meji l’Ekoo, aadoje lawọn to ṣẹṣẹ lugbadi ẹ

Faith Adebọla, Eko

Eeyan meji lo tun dagbere faye lai ro tẹlẹ nipinlẹ Eko, latari arun korona to ṣi n ja ran-in kari aye, leyi ti ko yọ orileede wa ati ipinlẹ Eko silẹ.

Ajọ to n ri si didena ajakalẹ arun lorileede wa, NCDC ati ileeṣẹ eto ilera Eko lo kede ọrọ yii lowurọ ọjọ Eti, Furaidee, wọn lawọn eeyan meji naa ti n gba itọju latigba ti wọn ti de ibudo itọju awọn alarun korona, ṣugbọn aisan lo ṣe e wo, ko sẹni to ri oogun iku ṣe.

Yatọ si tawọn to ku yii, wọn tun kede pe aadoje o din meji (128) lawọn to ṣẹṣẹ lugbadi arun naa l’Ekoo, wọn si ti ya wọn sọtọ fun itọju.

Ni apapọ, eeyan ti korona ti pa l’Ekoo di okoolerugba ati mẹsan-an (229).

Latari eyi, kọmiṣanna feto ilera ti ṣekilọ pe kawọn eeyan ma ṣe tura silẹ, ki wọn maa tẹle ofin ibomu ati ifọwọ, ikorajọpọ ero, bijọba ṣe la a kalẹ.

Leave a Reply