Korona wọ ọsibitu jẹnẹra ni Ṣagamu, ogun oṣiṣẹ lo ti mu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, o kere tan, ogun eeyan ninu awọn oṣiṣẹ ileewosan jẹnẹra ti ipinlẹ Ogun to wa ni Ṣagamu, iyẹn Ọlabisi Ọnabanjọ(OOUTH), lo ti ni arun Korona, gẹge ba a ṣe gbọ.

Ẹka awọn to n gba ẹjẹ awọn eeyan fun ayẹwo ni arun yii ti ṣẹyọ, bẹẹ ni wọn ni ẹnikan ninu awọn ogun eeyan to ti ni Korona yii tilẹ ti ko arun naa ran iyawo atawọn ọmọ rẹ meji, idile naa ti di onikorona bayii.

Iku ọkan lara awọn oṣiṣe ibẹ lo fa a tawọn yooku naa fi lọọ n ṣayẹwo Korona lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, nigba ti yoo si fi di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ogun eeyan layẹwo sọ pe wọn ti ni Korona ninu awọn bii aadọrin ti wọn wa lẹka yii. Bi ko ba tilẹ si iyanṣẹlodi tawọn dokita wa lẹnu ẹ lọwọ ni, awọn ti yoo ti lugbadi arun yii ni ọsibitu yii ko ba pọ ju bayii lọ, gẹgẹ  bi awọn ṣiṣẹ ibẹ ṣe sọ.

Ṣugbọn awọn tọrọ naa kan ko foju ire wo awọn alaṣẹ ọsibitu yii, wọn ni awọn ni ko pese nnkan  idaabobo fawọn, ti wọn n fi ẹmi awọn wewu bawọn ṣe n ṣayewo awọn onikorona, to fi di pe kokoro naa wọle sawọn naa lara.

Dokita agba lọsibitu OOUTH yii,  Peter Adefuye, loun ko lagbara lati sọrọ lori iṣẹlẹ yii, afi bi ileeṣẹ eto ilera tabi kọmiṣanna ibẹ ba foun laṣẹ. Nigba to ya ni atẹjade kan ti wọn ni ọfiisi rẹ lo ti wa jade sita, ohun ti wọn sọ sibẹ ni pe eeyan mẹjọ lo ni Korona ninu awọn oṣiṣẹ naa, ki i ṣe ogun eeyan.

Atẹjade ọhun fi kun un pe awọn abanilorukọ jẹ kan lo wa nidii iroyin akọkọ, wọn ni irọ gbuu ni, kawọn araalu ma gba wọn gbọ rara.

Leave a Reply