Koronafairairọọsi pa Aminu Logun, olori oṣiṣẹ lọfiisi gomina Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ijọba ipinlẹ Kwara ti fidi ẹ mulẹ pe arun Koronafairọọsi lo pa Aminu Logun, olori awọn oṣiṣẹ to jade laye lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lẹni ọdun mẹtalelaaadọrin.

Ninu atẹjade kan latọwọ akọwe iroyin Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, Rafiu Ajakaye, o ni lẹyin wakati diẹ ti esi ayẹwo ti wọn ṣe fun un fi han pe arun Korona ni Logun ni lọkunrin naa jade laye.

Gomina ti waa kede ọjọ meje lati fi daro oloogbe naa.

O ba ẹbi atawọn araalu kẹdun iku ọkunrin naa, bẹẹ lo ni awọn ẹbi yoo kede eto isinku rẹ laipẹ.

Ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun 2019 ni gomina yan Logun sipo olori oṣiṣẹ lọfiisi rẹ.

Ana ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn gbe oloogbe lọ sileewosan nigba ti àárẹ̀ ọhun ki i mọlẹ ko too di pe o dagbere faye nirọlẹ oni.

Leave a Reply