Koronafairọọsi: Ofin konilegbele n palẹmọ diẹdiẹ l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, ni Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti kede awọn igbesẹ tuntun pẹlu bi ofin konilegbele ṣe n kasẹ nilẹ diẹdiẹ nipinlẹ naa.

Lati ọsẹ to kọja ni ofin naa ti n fun awọn eeyan lanfaani diẹdiẹ lati jade, titi di ọsẹ meji si asiko yii si ni awọn ibudo ipejọpọ eeyan yoo maa ṣi diẹdiẹ.

Awọn eeyan Ekiti lanfaani, bii ti tẹlẹ, lati maa rin laarin aago mẹfa aarọ si mẹjọ alẹ lọjọ Aje, Mọnde si Ẹti, Furaidee, nigba ti konilegbele yoo wa lati asiko naa si ọjọ keji ni gbogbo ọjọ meje to wa ninu ọsẹ.

Lọjọ Abamẹta, Satide ati Aiku, Sannde, awọn eeyan ko ni i lanfaani lati jade di ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ti ṣọọṣi ati mọṣalaṣi yoo di ṣiṣi pada. Awọn ile ijọsin wọnyi ni yoo maa ṣe isin kan pere lọsẹ, bẹẹ ni wọn yoo tẹle ofin ilera.

Yatọ si awọn ile ijọsin wọnyi ti wọn yoo faaye silẹ laarin eeyan kan si ekeji, ko si apejọpọ eeyan to gbọdọ ju ogun lọ nibikibi.

Bakan naa nijọba ṣi awọn ẹnu ibode lati Ọjọbọ, Wẹsidee to kọja, nilana ofin tuntun tijọba apapọ ṣe.

Ogunjọ, oṣu yii, lawọn to wa nipele to gbẹyin nileewe alakọọbẹrẹ, ipele kẹta ileewe ati ipele to gbẹyin nileewe girama yoo wọle.

Ijọba tun ṣi Ọja-Ọba ati Ọja Bisi, niluu Ado-Ekiti, ṣugbọn wọn ni awọn to ni ṣọọbu nibẹ nikan ni ko maa taja, ko si ọja ẹgbẹ titi mọ.

Fayẹmi waa sọ pe ibomu ṣe pataki lasiko yii fun gbogbo ẹni to ba n rin nigboro, bẹẹ ni ikọ alamoojuto yoo maa ṣiṣẹ takuntakun lati fọwọ ofin mu awọn to ba tako alakalẹ nitori asiko ti gbogbo eeyan gbọdọ ṣọra fun aisan koronafairọọsi niyi.

 

Leave a Reply