Koronafairọọsi tun ti gbẹmi eeyan meji l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmisanna feto ilera nipinlẹ Ọṣun, Dokita Rafiu Isamọtu, ti kede pe arun koronafairọọsi ti pa eeyan meji mi-in bayii.

Ninu atẹjade kan ni kọmisanna naa ti sọ pe eeyan mẹrinla lo tun ti lugbadi arun naa lati ara awọn ti wọn ti ko o tẹlẹ.

Isamọtu ṣalaye pe bi awọn eeyan kan ko ṣe tẹle ilana tijọba n gbe kalẹ lati dẹkun itankalẹ arun koronafairọọsi nipinlẹ Ọṣun lo fa a to fi da bii ẹni pe awọn to n lugbadi rẹ n pọ lojoojumọ.

Ni bayii, eeyan marundinlọgọrun-un (95) ni wọn n gbatọju lọwọ lori arun koronafairọọsi l’Ọṣun, nigba ti eeyan meje ti dagbere faye nipasẹ arun naa.

Leave a Reply