Kulikuli ni Rianat fẹẹ lọ ra ti wọn fi pa a, ẹgbẹrun lọna ogun naira lawọn afiniṣowo ra apa ẹ l’Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileesẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu awọn afurasi afini ṣowo meji, Femi Adeniji ati Shittu Abdulmalik Wale, fẹsun pe wọn pa ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan, Yusuf Rianat, lasiko ti wọn ran an ko lọọ ra kulikuli ti wọn fẹẹ fi mu gaari wa ni agbegbe Amuyọ, niluu Ọffa, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara. Wọn kun un wẹlẹwẹlẹ, wọn si ta apa ẹ ni ẹgbẹrun lọna ogun naira.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi lede ni ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ niluu Ilọrin, o ṣalaye pe baba ọmọbinrin ọhun to n jẹ  Yusuf Taofeek, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa ẹka ti ilu Ọffa pe wọn ran Rianat ko lọọ ra kulikuli ti wọn yoo fi mu gaari wa lati ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ṣugbọn to ti di awati, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun lẹkun-un-rẹrẹ.

Ọkasanmi yii tẹsiwaju pe iwadii lo mu ki ọlọpaa mu Femi Adeniji, to si jẹwọ pe loootọ, oun loun pa oloogbe naa lati fi ṣowo, to si ti ta apa rẹ fun ọkunrin kan, Shittu Abdulmalik Wale, ti agboole Imam, niluu Offa, ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira, eyi lo mu ki wọn fi panpẹ ofin gbe awọn mejeeji.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Tuesday Assayomo, ti waa rọ gbogbo obi ati alagbatọ pe ki wọn kilọ fun awọn awọn ọmọ wọn ki wọn ye wa owo ojiji to le mu wọn maa fi eniyan ṣẹso.

Leave a Reply