Kumuyi fipa ba ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ titi to fi ku mọ ọn labẹ l’Okitipupa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Israel Kumuyi, ti foju bale-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda, l’Akurẹ, lori ẹsun fifipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹwaa kan lo pọ titi to fi ku mọ ọn labẹ.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye labule Akinfọsile, nijọba ibilẹ Okitipupa, ninu oṣu keji, ọdun ta wa yii.

Agbefọba, Uloh Goodluck, ṣalaye nile-ẹjọ, pe ọgọrun-un naira ni Kumuyi fi tan ọmọbinrin naa wọle ibi to ti fipa ṣe kinni fun un titi to fi dakẹ.

Uloh ni olujẹjọ ọhun ti ṣẹ si abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ati okoolelọọọdunrun din ẹyọ kan (319) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006 ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn fi kan an.

Bo tilẹ jẹ pe afurasi naa loun ko jẹbi lẹyin ti wọn ka ẹsun ti wọn fi kan an si i leti, sibẹ Onidaajọ Tọpẹ Aladejana ni ko ṣi lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn ilu Ọwọ titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun ta a wa yii, ni ile-ẹjọ sun igbẹjọ mi-in si.

Leave a Reply