Láṣòrè di igbakeji ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Ẹkun kọkanla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbakeji ọga agba patapata tuntun ti de ọga Ẹkun kọkanla ileeṣẹ ọlọpaa ti ibujoko rẹ wa niluu Oṣogbo. Orukọ rẹ ni Agunbiade Oluyẹmi Laṣore. Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Obokun, nipinlẹ Ọṣun, ni ọkunrin yii. Fasiti ilu Ibadan lo ti kẹkọọ gboye ninu imọ nipa ere idaraya ati eto ilera (Physical and Health Education).
O ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ nileewe Ṣẹkọna Grammar School, nipinlẹ Ọṣun, ko too darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa lọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun 1986.

O ti ṣiṣẹ ri nipinlẹ Rivers, Ọyọ, Eko, Jigawa, Kano, Ogun, Cross River, Anambra, Sokoto, Kebbi ati olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Leave a Reply