Laaarọ ọjọ keji ọdun Keresi, Taiwo lu ẹgbọn ẹ pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Laaarọ ọjọ keji ọdun Keresi, nigba ti inu awọn ọmọlẹyin Jesu kaakiri agbaye n dun pe ọdun ọdun yii ṣoju ẹmi wọn, ti wọn si n fi ẹbun ọdun ranṣẹ sira wọn, nigba naa lòkò ibanujẹ nla sọlẹ si idile Agbeni, idile Kristiẹni kan laduugbo Ẹdun, lagbegbe Wakajaye, n’Ibadan, nigba ti tẹgbọn- taburo wọya ija, ti wọn si ṣe bẹẹ ran ara wọn lọ sọrun apapandodo.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Agbeni Rẹmilẹkun, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) ati Agbeni Taiwo, ti wọn jẹ ọmọ iya atọmọ baba kan naa ni wọn jọ n ṣe Yahoo ti i ṣe àdàpè jibiti lilu lori ẹrọ ayelujara. Owo Yahoo yii lo dija silẹ laarin wọn.

Lọjọ ọdun Keresi lọwọ́ Rẹmi dẹ nidii iṣẹ jibiti lilu yii pẹlu bi ara ilẹ okeere kan ṣe fi owo nla kan ranṣẹ si i bo tilẹ jẹ pe a ko ti i mọ iye ọhun bayii. Owo yii ni Taiwo fi dandan le pe awọn jọ maa pin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu kejila, ọdun 2020 yii, ti wahala fi bẹ silẹ nigba ti ẹgbọn ẹ yari kanlẹ̀ pe ko si ohun to jọ ọ.

 

Ohun to fa ijakadi ree, to fi di pe tẹgbọn-taburo lu ara wọn titi ti aburo fi gbẹmi ẹgbọn ẹ, ti wọn si ṣe bẹẹ ko idile wọn sinu ibanujẹ ayeraye lati aarọ ọjọ keji ọdun Keresi, ọdun 2020 yii lọ.

Ọkan ninu awọn olugbe adugbo ọhun to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe “Ọmọ iya, ọmọ baba, ni wọn. Owo kan wọnu akanti ẹgbọn. Bi Taiwo ṣe ri i pe owo kan wọnu akanti ẹgbọn oun lo bẹrẹ si i yọ ọ lẹnu pe ko fun oun naa nibẹ, paapaa nigba to mọ pe Taiwo ti fun afẹsọna rẹ ninu owo yẹn.

“Awọn obi wọn ko si nile, baba wọn ko tiẹ gbe Ibadan mọ ni tiẹ. Awọn aburo wọn obinrin meji to wa pẹlu wọn ninu ile, fiimu ti awọn n wo lọwọ ti wọ wọ̀n wọn lara, eyi ko jẹ ki wọn ka ariwo ija ti wọn n gbọ nita si.

“Lẹyin ti wọn ti lu ara wọn niwaju ita wọn tan, ti awọn eeyan ti la wọn nija tan, ni Rẹmi wọnu ile lọ to si tilẹkun mọri ko baa le raaye sinmi nitori o ti rẹ ẹ. Taiwo waa lọọ fipa jalẹkun mọ ọn lori, o waa la àpótí ti wọn fi n jokoo nileedana mọ ọn lori. Loju ẹsẹ ni Rẹmi ṣubu lulẹ, to si j’Ọlọrun nipe.

 

“Bi Taiwo ṣe ri i pe ẹgbọn oun ti ku lo sa lọ, ti ẹnikẹni ko si ti i gburoo ẹ laduugbo yii lati igba yẹn.”

Ipe pajawiri ti Ọgbẹni Agbeni to jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti ati iyawo ẹ to jẹ olukọ gba lo jẹ ki wọn sare pada sile, ti wọn si ba oku ọmọ wọn ninu yara bo tilẹ jẹ pe awọn to pe wọn ko jẹwọ fun wọn lori foonu pe niṣe ni Rẹmi ti ku.

Ni nnkan bii aago mẹfa aabọ si meje alẹ ọjọ Satide ọhun ni wọn sinku Rẹmi, ẹni ọdun mẹrinlelogun to ṣẹṣẹ jade iwe giga, si ẹgbẹ ile wọn ni Wakajaye nibẹ.

Ninu iṣẹlẹ mi-in to fara pẹ́ èyi, diẹ bayii lo ku ki tẹgbọn-taburo mi-in tun gbẹmi ara wọn laduugbo Wakajaye yii kan naa.

Lọjọ keji ti Taiwo lu ẹgbọn ẹ pa ni ija nla kan bẹ silẹ laarin awọn tẹgbọn-taburo yii nigba ti eyi ọkunrin ti gbogbo eeyan mọ si Aríjẹ ati aburo rẹ, Aṣabi fija pẹẹta.

Obìnrinbìnrìn, Aṣakẹ to jẹ aburo naa lọọ gbe irin nla ka ẹgbọn ẹ mọnu ile, o ni  dandan ni ki oun gbẹmi ẹgbọn oun nitori oun ti ṣetan lati fi kinni naa fọ ọ lori pẹ́tẹ́pẹ́tẹ. Ẹmi eṣu gbe eyi ẹgbọn paapaa wọ, o ni loun naa ba loun yoo fi ada bẹ aburo oun lori sọnu. Bẹẹ apa iya wọn to wa nile ko ka wọn, ọpẹlọpẹ awọn alabaagbe wọn laduugbo.

Lẹyin ti awọn araadugbo gba irin lọwọ Aṣabi tan, niṣe lo tun sare lọọ ṣa ọpọlọpọ okuta ni titi, to si bẹrẹ si i lẹ ẹ mọ Aafaa Arijẹ lai bikita bi oko ba le ba awọn ara ẹni ẹlẹni ti wọn waa ba wọn pẹtu sija.

Ohun to kòòrè eṣu ni mimu ti wọn tete mu Aafaa Arijẹ wọle, ti wọn si tilẹkun mọ ara wọn pẹlu ẹ ko too di pe wọn fẹ̀yìn pọn ọn jade lọ. Bi bẹẹ kọ, afaimọ làlejò kan tabi meji ko ni i b’Ọlọrun nile ninu idile tiwọn naa.

ALAROYE gbọ pe iyawo meji ni Aafaa Arijẹ agba to jẹ baba wọn fẹ. Aafaa Arijẹ to jẹ ọmọ iyaale lakọbi ọmọkunrin rẹ nigba ti Aṣabi jẹ ọmọ iyawo, iya Aṣabi lo si wa nile lasiko ti ọmọ ẹ fija pẹẹta pẹlu ẹgbọn wọn patapata ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe a ko mọ ohun to fàjà laarin tẹgbọn-taburo yii, awọn to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe ọmọ lile gan-an ni l’Aṣabi, o si ti maa n ri Aafaa Arijẹ fin tipẹ ki iyẹn too pinnu lati kọ iwa ibajẹ naa fun un nigba to tun bẹrẹ si i wẹnu si i lara nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

 

Ko ti i to wakati mẹrin lọ si iṣẹlẹ yii, iyẹn ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, Sannde ijẹta ni ibẹrubojo tun ba awọn olugbe adugbo Ẹdun, ni Wakajaye, n’Ibadan yii, nigba ti wọn deede ri ogunlọgọ awọn ọdọmọkunrin atawọn ọdọmọbinrin ti wọn wọ aṣọ dudu pẹlu ina abẹla lọwọ wọn ti wọn si bẹrẹ si i kọrin kiri agbegbe naa.

Nigba ti awọn alaṣọ dudu ti wọn tanna yin-in-yìn-yin lọwọ yii too sun mọ ọpọ eeyan ni wọn too mọ pe awọn ẹgbẹ Rẹmi nileewe ni wọn n ṣe iwọde alẹ ọhun lati ṣèdárò iku ọrẹ wọn to wọ kaa ilẹ lọ yika agbegbe naa.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, akọroyin wa gbọ pe akanṣe adura lawọn olugbe adugbo Ẹdun, ni Wakajaye, n’Ibadan, kan n ṣe ni gbogbo igba bayii, nitori ẹru n ba wọn ko ma baa jẹ pe ègún kan lo ṣokunfa awọn iṣẹlẹ aburu mejeeji to jọ ara wọn yii.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: