Laaarọ kutu Mọnde, awọn obinrin meji ku lasiko ti wọn n lọ sọja l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Idi iṣẹ ẹni la ti n mọ ni lọlẹ lawọn obinrin meji kan ti wọn pade iku ojiji lọjọ Mọnde ọsẹ yii fi ọrọ wọn ṣe ti wọn fi tete mu ọna ọja ti wọn ti n ra ẹja pọn niluu Abẹokuta. Ṣugbọn niṣe ni mọto ti wọn wọ lọọ kọ lu tirela to bajẹ sọna, l’Abule Adedẹrọ, bi wọn ṣe dagbere faye niyẹn.

Aago mẹfa idaji ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ yii waye, ni Mọnde, ọjọ keje, oṣu kẹfa yii.  Kọbapẹ ni mọto ayọkẹlẹ Nissan tawọn obinrin naa wọ ti gbe wọn pẹlu awọn ero ọkọ mi-in, ilu Abẹokuta ni wọn si n lọ.

Igba ti wọn de Abule Adedẹrọ, loju ọna marosẹ Eko s’Abẹokuta ni dẹrẹba lọọ kọ lu tirela to bajẹ sọna, nigba naa lawọn obinrin meji yii dagbere faye, awọn mẹta mi-in si fara pa.

Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣalaye nipa ijamba naa. O ni dẹrẹba ọkọ Nissan naa lo n sare ju, ti ko wo ti pe ilẹ ko ti i mọ daadaa. Ere to pọ ju yii ati airiran daadaa nigba ti ilẹ ko ti i mọ to lo ni o fa a ti asidẹnti yii fi waye.

Owo to le ni ẹgbẹrun lọna igba naira ni wọn ba lara awọn obinrin meji to doloogbe yii, owo ti wọn fẹẹ lọọ fi ra ẹja ti wọn n ta ni.

Wọn ba ẹgbẹrun lọna ọgọjọ din diẹ naira (153,620) lara ọkan, wọn si ba ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọrin (77,000) lara ẹni keji. Awọn mọlẹbi wọn ni wọn ko owo naa fun gẹgẹ bi Alukoro TRACE ṣe sọ.

Mọṣuari ọsibitu Ijaye ni wọn gbe awọn oku meji naa lọ.

Ajọ TRACE waa kilọ fawọn awakọ ti mọto wọn ba bajẹ soju ọna lati maa gbe e kuro lọna kia, ko ma baa maa da ijamba silẹ bii eyi.

Bakan naa ni wọn rọ awọn awakọ pe ki wọn yee sare asapajude loju popo, paapaa lasiko ti wọn ko ba riran daadaa bii idaji kutu ati ọwọ alẹ.

Leave a Reply