Laaarọ kutu ọjọ Keresi, eeyan meje ku ninu ijamba ọkọ ni Ṣagamu, mẹfa ku ni marosẹ Eko s’Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi,  Abẹokuta

Ko din leeyan meje to ku, ti meje mi-in tun fara pa lori afara Ọsọsa, loju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin, lọjọ ọdun Keresimesi ti i ṣe Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2021. Lọjọ yii kan naa lawọn mẹfa mi-in tun dero ọrun ni marosẹ Eko s’Ibadan.

Ni ti ijamba to ṣẹlẹ lori biriiji Ọsọsa yii, aago mejila oru kọja ogun iṣẹju lo waye gẹgẹ bi ọga FRSC Ogun, Ahmed Umar, ṣe ṣalaye.

O ni bọọsi kan lo n sare buruku, to n ya awọn ọkọ yooku silẹ loruganjọ naa, afigba to si ko si wahala, to fi tiẹ gba ẹmi eeyan meje lọjọ ọdun.

Agbalagba ọkunrin mẹta ati obinrin mẹrin ni iku ojiji naa kan nigba ti ijamba ọhun waye. Ọkunrin mẹta ati obinrin mẹrin si lawọn meje mi-in to tun fara pa bi Umar ṣe sọ.

Ile igbokuu-si to wa ninu Ọsibitu Jẹnẹra Ijẹbu-Ode, ni wọn gbe awọn oku lọ, nigba ti wọn fun awọn to ṣeṣe nitọọju pajawiri nibi iṣẹlẹ naa.

Wọn ko ti i ko ifa iṣẹlẹ aburu yii nilẹ tan ti ajọ FRSC tun fi gbọ pe ijamba ọkọ mi-in tun ti waye ni marosẹ Eko s’Ibadan, ati pe eeyan mẹfa tun ti gbọna ọrun lọ lọjọ Keresimesi kan naa.

Yatọ sawọn mẹfa to ku yii, awọn mejila ni wọn ni wọn tun fara pa.

Ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye doju kọ ileeṣẹ to n tun ọna ṣe ti wọn n pe ni ELANLAN, aago mẹta oru kọja ogun iṣẹju loun si ṣẹlẹ ni tiẹ.

Alaye ọga FRSC ni pe bọọsi ti nọmba ẹ jẹ  MKA 567 XZ ati tirela ti nọmba ẹ jẹ  XF854KTN ni iṣẹlẹ naa kan.

Umari ṣalaye pe ohun to fa ijamba yii ni awọn idiwọ to wa loju ọna yii latari bi wọn ṣe n ṣe e lọwọ, ere asaju ati aile ko mọto nijaanu mọ lo fa a.

Bi ijamba ṣe waye ni wọn ti n sare gbe awọn to fara pa lọ sileewosan oriṣiiriṣii, wọn gbe awọn kan lọ si ileewosan ijọba Eko ti wọn n pe ni imajẹnsi ( Emergency) l’Ọjọta. Wọn gbe awọn mi-in lọ si  Divine Touch, n’Ibafo, wọn si gbe awọn kan lọ sileewosan Ọlabisi Ọnabanjọ, ni Ṣagamu.

Ṣugbọn ni tawọn to ti ku loju-ẹsẹ, mọṣuari Ọsibitu Idẹra ni wọn ko wọn lọ.

Wọn ri ẹgbẹrun mẹtadinlaaadoje ati diẹ Naira ( 127, 900) nibi iṣẹlẹ yii.

Fun alaye lẹkun-un-rẹrẹ nipa awọn iṣẹlẹ yii, FRSC ni kawọn eeyan to ba fẹẹ mọ si i nipa ti Ọsọsa lọ sọfiisi awọn to wa n’Ijẹbu-Ode, kawọn ti marosẹ Eko s’Ibadan lọ si ọfiisi FRSC Ibafo, wọn yoo mọ ohun ti wọn ba fẹẹ mọ si i nipa iṣẹlẹ naa.

Ajọ alaabo yii ni ohun tawọn n kilọ ẹ ni gbogbo igba ree, pe ijamba ko mọ ọjọ ọdun, ko sigba ti ko le ṣẹlẹ, nigba teeyan ba ti faaye silẹ fun un pe ko waye.

Wọn ba ẹbi awọn tijamba kan kẹdun, wọn si tun rọ awọn awakọ lati gbọ ikilọ tawọn n fojoojumọ ṣe fun wọn.

Leave a Reply