Laaarọ Mọnde ni Tunde lọọ digunjale l’otẹẹli l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Idaji kutu ọjọ Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ni Tunde Esuruoṣo atawọn yooku rẹ ti wọn  jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ, digun ja awọn eeyan lole lotẹẹli LADIS, Ọbantoko, l’Abẹokuta. Nibi to ti n pitu ẹ naa lawọn ọlọpaa ti de, ti wọn mu un ṣinkun.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye ninu atẹjade ẹ pe awọn kan ni wọn pe teṣan ọlọpaa Ọbantoko ni fẹẹrẹ naa, pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n ko ipaya ba awọn eeyan to wa ninu otẹẹli ọhun, wọn n ja wọn lole, wọn si ti ko hilahilo ba wọn.

DPO SP Ignatius Alimiekena ko awọn ikọ rẹ, o di ileetura naa. Wọn tilẹkun mọ gbogbo awọn to wa nibẹ, wọn ko faaye ati-jade kuro ninu ọgba naa fun ẹnikeni.

Eyi lawọn ẹlẹgiri naa ṣe darapọ m’awọn eeyan inu otẹẹli, ti wọn ṣe bii ọmọ gidi nigba t’ọlọpaa de.

Awọn ọlọpaa naa ti jagbọn wọn, wọn wọnu otẹẹli yii, wọn si bẹrẹ si i yẹ ara kaluku wo finni-finni lati mọ ẹni to lẹbọ lẹru.

Nibi ti wọn ti n ṣe bẹẹ ni wọn ti ba ibọn  danku kan lara Tunde Esuruoṣo, wọn ri ọta ibọn kan ti wọn ti yin lọwọ  ẹ pẹlu, ni wọn ba mu un.

Nigba to n dahun ibeere awọn ọlọpaa, Tunde jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ loun. O ni ọkan ninu awọn ẹgbẹ oun tawọn n pe ni Scatter lo foun nibọn naa.

CP Lanre Bankọle ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka iwadii, ki wọn wa awọn toku rẹ ri laipẹ. Bakan naa lo kilọ fawọn olotẹẹli pe ki wọn maa mọ iru awọn eeyan ti wọn yoo maa fun ni yara lọdọ wọn, nitori olotẹẹli to ba gba arufin si yara ko ni i lọ lai jiya, ijọba yoo mu oun naa gẹgẹ bii ọdaran ni.

Leave a Reply