Laaarọ yii, Buhari pade Jonathan ninu Aso Rock

Olori ijọba Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣe akanṣe ipade kan loni-in yii pẹlu aarẹ ilẹ wa ana, Ọmọwe Goodluck Jonathan, ninu Aso Rock. Lori iṣẹ pataki kan ti ajọ awọn orilẹ-ede Iwọ-oorun Afrika (ECOWAS) gbe fun un lo lọọ tori ẹ ri Buhari.

Ede-aiyede kan n fẹẹ bẹ silẹ ni orilẹ-ede Mali, ki ọrọ naa too wa di wahala ti apa ko ni i ka mọ ni awọn olori orilẹ-ede West Africa ṣe ni o yẹ ki wọn gbe igbimọ kan dide ko le tete ri si ọrọ naa. Igbimọ yii ni wọn fi Jonathan ṣe olori rẹ, bi iṣẹ naa si ṣe fẹẹ lọ si lo jẹ ki Jonathan tori ẹ de Aso Rock.

Leave a Reply