Lọjọ kan ṣoṣo, arun Korona pa eeyan marun-un nipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wọn ti kede bayii pe laarin ọjọ kan ṣoṣo, eeyan marun-un ni wọn ti padanu ẹmi wọn sọwọ ajakalẹ arun Koronafairọọsi.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto ilera l’Ọṣun, Dokita Rafiu Isamọtu, fi sita lo ti sọ pe ninu atẹjade to jade latọdọ ajọ Nigeria Center for Disease Control (NCDC) lalẹ ọjọ Tusidee leleyii ti di mimọ.

Isamọtu ṣalaye pe yatọ si awọn marun-un ti wọn ti ku, eeyan mejilelogun ni wọn tun ti lugbadi arun naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

O ṣalaye pe inu ijọba ko dun si bi awọn kan ko ṣe bikita fun ẹmi ara wọn pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ ti wọn fi mu ọrọ itankalẹ arun Korona.

O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti wahala arun naa kọkọ bẹrẹ lọdun to kọja, ipinlẹ Ọṣun nikan ni ko ni akọsilẹ eeyan pupọ ti wọn lugbadi arun naa, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ṣe ni kinni ọhun n ran bii ina ọyẹ.

Isamọtu ta awọn araalu lolobo pe ogun arun naa le ṣẹ ti onikaluku ba bẹrẹ si i bikita fun ilera ara wọn, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, ki wọn si maa gbe igbe aye imọtoto.

Leave a Reply