Laarin ọjọ mẹrin ti Oriṣabunmi ku, ẹgbọn ẹ ku, aburo ẹ naa ti tun ku o

Aderounmu Kazeem

Ko ṣeni to gbọ nipa iṣẹlẹ iku ojiji to tun ṣẹlẹ ninu mọlẹbi gbajumọ oṣere tiata nni, Fọlakẹ Arẹmu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Oriṣabunmi, ti wọn ko maa ba wọn kẹdun gidigidi, bẹẹ lawọn eeyan n sọ pe, dajudaju iku to pa eeyan mẹta ninu mọlẹbi kan naa laarin osẹ kan sira wọn ki i ṣe oju lasan mọ rara.

Ireti awọn eeyan lẹyin iku Oriṣabunmi ni bi ikede yoo ti ṣe waye nipa eto isinku ẹ, paapaa ipa ti awọn oṣere ẹgbẹ ẹ yoo ko lati fi ṣẹyẹ ikẹyin fun un, ṣugbọn ṣadeede ni iroyin gba lu wi pe ẹgbọn Oriṣabunmi, Steve Onisola, ẹni ti obinrin naa tẹle ti jade laye lẹyin bii wakati mẹrinlelogun ti aburo ẹ papoda.

Ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin (71) ni wọn pe oloogbe ọhun, ohun tawọn eeyan si ro ni pe boya aarẹ agba lo fa a, tabi ko jẹ pe iṣẹlẹ ọhun kan waye bẹẹ ni.

Eyi to waa jẹ agbọsọgbanu iroyin ni eyi to gba igboro kan pe lọjọ Abamẹta, Satide ana yii, ni abikẹyin awọn Oriṣabunmi, Arabinrin Janet Ademọla, naa tun jade laye.

Okan lara awọn mọlẹbi wọn, Gbenga Oniṣọla, gan-an lo kede iku ojiji yii, eyi gan-an lo mu awọn eeyan maa sọ pe dajudaju ọrọ naa ki i ṣe oju lasan mọ, nitori bawo ni ọmọ iya mẹta ṣe le ku laarin osẹ kan sira wọn lai ki i ṣe ijanba mọto.

Ṣaaju asiko yii ni ana Oriṣabunnmi, Alhaji Abdul-Fatai Adeniyi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Dan Kazeem, ti ba akọroyin wa sọrọ lori bi eto ayẹyẹ isinku Oriṣabunmi, yoo ṣe waye. Alaye to si ṣe ni pe awọn ẹgbẹ oṣere tiata ti wọn wa ni Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti Oriṣabunmi, n gbe ti bẹ awọn mọlẹbi ki wọn jẹ ki awọn pari eto ti awọn n ṣe lọwọ lori ipalẹmọ ayẹyẹ isinku naa.

Dan Kazeem sọ pe ni kete ti awọn Tampan ba ti sọ pe o ya lawọn yoo kede igba ti eto isinku Oriṣabunmi yoo waye, ati pe titi di asiko yii ni oku obinrin naa ṣi wa ni ile igbokuupamọsi.

Bi eto nipa isinku Oriṣabunmi si ṣe wa niyẹn o, ki iroyin iku ojiji aburo ẹ too tun gba igboro kan, ohun tawọn eeyan si n beere ni pe ki lo n ṣẹlẹ gan-an!

Wọn ni lori ọrọ Oriṣabunmi gan an lo yẹ kawọn eeyan ti kiyesi i, nitori pupọ ninu awọn eeyan ti wọn pade ẹ lagbo ariya lasiko Keresimesi, atawọn ti wọn jọ wa ni lokeṣan ere ni nnkan bi ọjọ mẹta si mẹrin ṣaaju iku ojiji to pa a ni wọn n sọ pe Oriṣabunmi ti awọn ri ko jọ bii ẹni ti iku ojiji yoo sare pa bẹẹ, ati pe gbogbo iṣẹlẹ ọhun ki i ṣe oju lasan. Ohun to waa pamọ bayii, oju Ọluwa lo to o o.

Leave a Reply