Laelae, emi o ni i da sọrọ Alaaji atawọn iyawo ẹ mọ o

Alaaji ti n dagba. Fun odidi ọjọ mẹta, ko jade, ere egele toun atawọn iyawo ẹ meji jọ ṣe yẹn ni. Emi o mọ ohun to de tọrọ naa fi le to bẹẹ fun un. N o mọ boya o tun lọọ ṣe nnkan fun Iya Dele naa lẹyin gbogbo wahala ti Aunti Sikira ti foju ẹ ri. Ohun ti mo ṣe ro pe o le je bẹẹ ni pe bi inu Aunti Sikira ṣe n dun kiri inu ile, to n rẹrin-in si gbogbo ẹni to ba ti ri, bẹẹ naa ni inu Iyaale mi n dun. Iya Dele ki i ṣoroo mọ ti inu ẹ ba n dun, oriṣiiriṣii orin Barisita lo maa maa jade lẹnu ẹ, tabi ko bẹrẹ orin awọn Kerubu ati ti Sẹlẹ, kẹ ẹ ti mọ pe idunnu ṣubu layọ niyẹn.

N o fẹẹ da si i tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti mo ri i pe ko gbadun, mo yọju si i. Ohun ti mo si fẹẹ sọ fun un ni pe ko lọ si ọsibitu bo ba mọ pe ara oun ko ya, paapaa laye Korona yii, ki n si tun sọ fun un pe ko yẹra fawọn iyawo ẹ ti wọn fẹran ‘kinni’ yii ju ounjẹ lọ. Mo sọ fun un pe agba loun naa n da yii, ki i ṣe ọmọde mọ, baba to ba ti le ni sẹminti, o loju ere to le ṣe, o si ni ibi to yẹ ki wọn ti maa ba a. Safu gan-an lo n bẹ mi ki n yọju si i. Mo yọju si i, ṣugbọn ko jẹ ki n sọrọ o. Lo ba n sọ awọn oyinbo ẹgbẹ to maa n sọ yẹn, awọn oyinbo ti o gbowo jade nibi kan.

O ni kin ni mo miini, kin ni emi disaya, kin ni pilaani mi. O ni ta lo sọ femi pe oun ti dagba, ti oun ba ra emi mu nibi ti mo wa yẹn, mo maa maa ṣe lailaa ni, nigba toun ba tẹ irin tutu semi lara. Niṣe ni mo n wo ẹnu ẹ. Awọn aṣa oriṣiiriṣii tiẹ ti waa kun ẹnu Alaaji, awọn aṣa ti n o gbọ ri. O ni kemi ma le awọn alaaanu lara oun, pe awọn ti wọn n tun ẹjẹ oun ṣe niyẹn, awọn ti wọn n foun loogun ajidewe. O ni bo ba jẹ bi emi ṣe ri lawọn to ku ri, oun iba ti ku tipẹ. Niṣe ni mo pariwo, ‘haa!,’ abi iru asọnilẹnu ọkunrin wo niyi. A bẹ ẹ gbọ’hun to wi ni!

O ni boun ba waa ba mi, emi a maa gbedii sa, ma a ni wọn o gbọdọ fọwọ kan mi lọmu, wọn o gbọdo fọwọ kan mi nidii, awọn to dẹ laiki oun, ti wọn n ko oun mọra, ti wọn n rọọṣi oun bii indomi, mo tun fẹẹ maa kọmpileeni. O ni ki emi fi wọn silẹ ki wọn jaye ori wọn o. Mo yaa dide, mo ni mo ti gbọ o. Aanu abiyamọ lo ṣe mi ni, ko ma jẹ aiyaara to n ṣe e ti ko fi jade pọ ju bẹe lọ ni, ko si mọ ohun to ba fa aisan si i lara, ko le maa ṣọra fun un. O ni mo ṣe e, pe akoko ti to ki emi lọọ gba iṣe adura, tabi iṣẹ oniwaasu, ki n le maa ṣalaye mareeji fawọn eeyan.

Niṣe lo da bii pe o ti ni mi sinu tẹlẹ, abi ki la ba lọ, ki la ba bọ, to wa n da awọn ọrọ silẹ bẹẹ fun mi wẹẹrẹwẹ. A lo ni ki loun ṣe tẹnikan ko ṣe ri, pe awọn baba oun loun fiwa jọ. Mo ni baba ẹ wo, baba ẹ temi mọ, iyawo mẹrin lo fẹ ni ti suna Anọbi, mo si mọ itan bawọn iyawo naa ṣe lọ. O ni ki i ṣe mẹrin ni baba oun fẹ, pe mẹjọ ni. Mo ni ko sigba kan ti obinrin ju mẹrin lọ ninu ile baba ẹ ri, biyawo kan ba lọ lo n fẹ omi-in, ohun ti wọn ṣe pe mẹjọ niyẹn. O ni ki emi ba ara mi da sọhun-un, baba oun ti oun n wi kọ niyẹn, pe Alaafin ni baba toun. Mo ni, ‘họọ!’

O ni emi o ri iye awọn ọmọ keekeeke to wa lọdọ baba, ti wọn n tọju baba, ti wọn  n fun baba ni ajidewe to daa, pe baba tun ṣẹṣẹ mukan si i bayii ni; wọn o si bara wọn ja, ere ni wọn jọ n ṣe, ewo lo waa mu emi ti ara mi n gbona bẹẹ. N ko fesi kan mọ o, mo yaa jade. Nigba ti mo si riyawo ẹ, iyẹn Safu, tiyẹn waa sare ba mi loke, mo ni ko ma waa sọrọ ọkọ wọn fun mi mọ o, nitori emi o ni i da sọrọ oun atawọn iyawo ẹ mọ, n ko fẹ arifin kankan, nitori jẹẹjẹ mi ni mo n lọ. Ni Safu ba ni, ‘Iyaa mi, ẹ ẹ si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun mi!’

Ni mo ba ko, ni mo ba ro fun un o. Mo ṣe gbogbo alaye bi mo ṣe lọ sibẹ ati awọn ọrọ ti mo sọ, pẹlu awọn esi ati ọrọ kobakungbe ti Alaaji sọ si mi. Bi mo si ṣe sọrọ tan, niṣe ni Safu ma gbẹrin. O ma n rẹrin-in yii lọ ko sinmi ni o. Ni mo ba n wo o. Nigba ti ẹrin ẹ ko nitumọ si mi ni mo ni ṣe ẹrin lọrọ mi gba bayii, abi o n fi mi ṣe yẹyẹ pe Ọlọrun mu mi ni, bẹẹ oun lo si ni ki n lọ. Lo ba ni ki i ṣe bẹẹ, pe oun ṣẹṣẹ ri ibi ti iṣoro ti wa ni, pe oun ṣẹṣẹ ri iṣoro Alaaji ati ohun to n ṣe e gan-an ni. Mo ni ki lo n ṣe e. O ni ko si ẹni ti Alaaji fẹran ju mi lọ ni, ifẹ mi lo n ti i kiri.

Mo ni ifẹ wo lo n sọ nipa ẹ, ifẹ jakujaku wo niyẹn. O ni gbogbo ohun ti Alaaji n ṣe yẹn, nitori pe emi o fun un lohun to n wa ni gbogbo igba, n ko jẹ ko maa gun mi nigba ta ba ti fẹ, o waa n wa ọna lati fi han mi pe oun le fiya jẹ mi, iyẹn lo ṣe n fẹgba, to n fẹ awo, pe awọn ti mo ri yẹn, o le fẹran wọn o, ṣugbọn ko sẹni to maa fẹran ju mi lọ ninu gbogbo wọn. Nigba ti yoo ba ọrọ jẹ lo ba ni emi ti rofọ fun wọn ni, pe awọn to ba emi ṣe ẹfọ ti mo ro fun un nigba kekere wa, wọn ti ri i ṣe ju, ko le fẹran ẹlomi-in mọ, gbogbo awọn kan n ba ẹlẹja yan an ni.

Haa, Safu, ẹnu ọmọ yẹn gbọrọ o. Ọrọ to kuku n sọ ko ye emi o, mo si wi bẹẹ fun un. Iru ifẹ wo niyẹn, ko kuku tiẹ pe e nifẹẹ, o ni lọọfu. Iranu.

Laarin oṣu kan pere, Safu si ti waa di kori-kosun mi, afi bii pe a ti mọra lati kekere, bii pe ọwọ mi ni wọn bi i si ni. Ko si ọrọ ti ko le sọ fun mi, ko si si ohun kan to ti ṣe kọja ti ko ti i sọ fun mi. A oo jọ rojọ titi ni ṣọọbu, ta a ba ti tun dele, to ti ṣe ounjẹ tan, yoo tun waa ba mi rojọ diẹ ko too lọọ ba baba yamiyami! Agbaaya, enranu!

Emi naa fi han an pe mo fẹran ẹ ṣaa o. Lọjọ ti mo fẹẹ fun un lowo, n ko fun un ni ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn aabọ mọ, ohun to si fa a ni pe lọjọ naa, loju mi, apo irẹsi mẹwaa lo tun ta. Mo waa ri i bo ṣe n ṣe ọrọ aje ẹ, niṣe lemi naa n wo o bii iran. Awọn ọmọ mi tibi ko tiẹ mira, wọn kawọ gbera ni.  Iye to ta tibi naa lo tun ta a, niṣe ni mo ṣẹṣẹ ni ki wọn lọọ ko apo irẹsi si i wa lọdọ awọn Akin. Nigba ta a waa dele lọjọ yẹn, mo waa ka gbogbo owo ẹ, o jẹ ẹgbẹrun mejilelaaadọta ati aabọ, n ko si yọ kọbọ ninu ẹ, iye ti mo ko fun un naa niyẹn.

Nigba ti mo ko o fun un, o ni kin ni mo fẹ ki oun ra. Mo ni owo ẹ ni, mo waa ṣalaye bo ṣe jẹ fun un pe lori ọja to ta ni owo naa ti yọ. Diẹ lo ku ko gbe mi ṣubu nigba to ra mi mu. Igba to jaja sọ mi silẹ, niṣe lo wo kalẹ to n sunkun. Mo ni ki lo fa iru igbe bẹẹ! O ni lati ọjọ ti oun ti daye, oun ko fọwọ ka iru owo bẹẹ ko jẹ toun ri laye oun ni. Haa, oriṣiiriṣii nnkan lo n ṣẹlẹ o, ẹni ti ko mo ni ko mọ, ka ṣa maa ṣe rere.

Leave a Reply