L’Agbado, Diran ba iyawo ẹ atijọ lo pọ lotẹẹli, lo ba gbabẹ ku

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi wọn ba n ṣadua pe ka ma gba ibi ta a gba wa saye lọ sọrun pada, ogidi adura tawọn ọkunrin ko gbọdọ fi ṣere ni. Afi ti pe adura naa ko gba fun ọkunrin abaniwale kan, Diran Elijah, ẹni to ba iyawo to ti kọ silẹ tẹlẹ ṣere ifẹ tan lotẹẹli, to si gbabẹ dero ọrun.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Sannde to kọja yii niṣẹlẹ buruku naa waye lotẹẹli kan l’Agbado, ipinlẹ Ogun, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ. Ohun tawọn to mọ nipa ẹ sọ ni pe tọkọ-tiyawo ni Diran ati obinrin naa, Idowu, tẹlẹtẹlẹ.

Wọn ni wọn fẹra wọn pẹ debii pe wọn bimọ meji funra wọn, ṣugbọn awọn ọmọ ti wọn bi funra wọn naa ko ye, niṣe ni wọn ku. Nigbẹyin ṣa, awọn mejeeji fi ara wọn silẹ, wọn ko fẹra mọ.

Lẹyin ikọsilẹ yii ni Idowu fẹ ọkọ mi-in, o ti bimọ meji fun ọkọ tuntun yii bayii. Diran naa fẹyawo mi-in lẹyin to kọ Idowu silẹ, iyawo tiẹ naa si ti bimọ kan fun un.

Ṣugbọn oju to ti mọ’ni ri ko le pe oun ko mọ ni mọ, awọn eeyan sọ pe iyẹn lo fa a ti Diran Elijah ṣe tun bẹrẹ si i pe Idowu laipẹ yii, pe ko wa kawọn tun jọ maa rira awọn bii ti tẹlẹ.

A tilẹ gbọ pe Idowu yawo nileefowopamọ Microfinance kan, ko si ri owo ọhun da pada, awọn iyẹn si n da a laamu debii pe wọn ti le e jade nile toun atọkọ tuntun to fẹ n gbe, ṣọọṣi ni wọn  lobinrin naa n sun si pẹlu awọ ọmọ ẹ meji bayii.

Iṣoro to de ba a yii ni wọn ni Elijah ṣe sọ fun un pe ko ma bẹru, oun yoo ba a san ninu gbese naa, ko ṣaa wa si otẹẹli, kawọn jọ rira awọn.

Adehun ati rira naa ni Idowu mu ṣẹ ni Sannde to kọja, to fi lọọ pade ọkọ rẹ atijọ lotẹẹli, ti wọn jọ ba ara wọn sun bii ti tẹlẹ, ko too di pe wahala de lẹyin ibalopọ ọhun.

Bi wọn ti ṣere ifẹ tan ni wọn ni Elijah sọ pe o rẹ oun, oun fẹẹ sinmi. Nibi to ti n sinmi naa ni mimi rẹ ti yipada, to bẹrẹ si i mi gulegule, ti ko si gbadun mọ.

Eyi lo mu Idowu pariwo pe kawọn eeyan gba oun o, n ni wọn ba sare debẹ lati ṣaajo Elijah, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, ọkunrin abaniwale tọjọ ori ẹ ko ju aadọta ( 50) lọ naa ti dero ọrun.

Wọn fa Idowu fọlọpaa, ṣugbọn awọn ẹbi Elijah sọ pe ki wọn fi i silẹ. Wọn lawọn ko ni ẹjọ kankan tawọn fẹẹ ba a ro, nitori amuwa Ọlọrun lohun to ṣẹlẹ, ko si kinni kan tẹnikan le ṣe si i.

Ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, ti i ṣe ibi ti wọn ti bi Oloogbe Diran Elijah ni wọn gbe e lọ lati sinku rẹ, wọn ti gba beeli Idowu tawọn ọlọpaa mu tẹlẹ naa, awọn ẹbi tọrọ kan si ti ni awọn yoo yanju ẹ laarin ara awọn.

Leave a Reply