Laipẹ yii ni wahala ẹgbẹ oṣelu PDP yoo rokun igbagbe – Oyinlọla

Florence Babaṣọla

Alaga igbimọ to n pẹtu saawọ aarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP niha Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, ti sọ pe wahala to n mi ẹgbẹ naa logbologbo bayii yoo rokun igbagbe laipẹ.

Ninu ọrọ ti Oyinlọla ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun sọ niluu Oṣogbo ‘Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe o n ṣe ọmọlooku bẹẹ ni lọwọlọwọ, o daju pe ogo ẹgbẹ naa yoo pada laipẹ.

O ṣalaye pe loootọ ni iṣẹ ti wọn gbe le oun lọwọ naa lagbara pupọ, to si gba ọgbọn Ọlọrun, sibẹ, oun ni idaniloju pe gbogbo awọn ti inu n bi ni wọn yoo jeburẹ laipẹ, ti gbogbo wọn yoo si pada sabẹ orule kan ṣoṣo.

Oyinlọla fi da gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ loju pe igbimọ oun yoo ṣamulo iwe-ofin ẹgbẹ ninu gbogbo nnkan ti awọn ba n ṣe lati ri i pe ẹgbẹ wa niṣọkan ṣaaju idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ekiti ati Ọṣun pẹlu idibo apapọ orileede yii ti ọdun 2023.

O ni idi pataki toun fi pepade ọhun ni lati sọrọ papọ, ki gbogbo awọn fikunlukun lori ohunkohun to n fa gbọnmi-si-i omi-o-to-o ninu ẹgbẹ naa, ki awọn si wa ọna mu gbogbo eeyan wa niṣọkan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ko si bi ẹgbẹ naa ṣe le tẹsiwaju lati gba ipo rẹ pada lorileede yii lai fi ọja kan ṣoṣo sonu, o ni oun ti bẹrẹ iṣẹ naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, awọn si tun n lọ sipinlẹ Ekiti laipẹ, lẹyin naa lawọn yoo fi abọ jẹ awọn to gbesẹ fun oun.

Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, Sọji Adagunodo, o ke si gbogbo awọn ti wọn ni ikunsinu kan tabi omi-in lati fọwọ wọnu, ki wọn si jẹ ki gbogbo wọn ṣiṣẹ papọ fun idagbasoke ẹgbẹ l’Ọṣun ati lorileede yii.

Leave a Reply