Lalẹ ọjọ ti mo ra ilẹ Oṣodi yẹn, gobe ṣẹlẹ nile wa

Alaṣepe ni Ọba Ọlọrun. Nigba to ba ṣe tan lati ṣe oore fun ẹda, yoo ṣe kinni naa ni aṣepe ni. Gbogbo ohun to n ja mi laya lori ọrọ ilẹ ti mo fẹẹ ra, Ọlọrun si ṣe e pe patapata. Ohun to tiẹ waa jẹ iyanu ni pe laarin ọjọ perete ni, laarin ọjọ diẹ, ohun gbogbo si yanju tan paapaapaa. Emi naa ko le sọ pe bayii ni Ọlọrun ṣe ṣe e, mo ṣaa kan ri i pe o n ṣe e naa ni. Wọn pe mi silẹ, mo n ronu pe nibo ni ki n ti ri owo, pe mo fẹẹ yawo, owo si de sọwọ mi lai ya kọbọ. O ya awọn onibanki gan-an lẹnu nigba ti wọn de ti mo ni mi o yawo mọ.

Niṣe ni wọn n beere pe ṣe awọn ṣẹ mi ni, ki lo de, awọn ti pari iwe mi, nitori wọn sọ fawọn ni ẹdikọta pe Iya Biọla ki i ṣe eeyan bẹẹ, iye to ba fẹẹ ya ki wọn ya a. Mo ni n o ma mọ pe mo lorukọ to bẹẹ lọdọ awọn ara banki o, pe Ọlọrun yoo maa ṣe apọnle ati iyi fun awọn naa. Bi mo ṣe ra mọọti fun wọn ti mo tun fun awọn to fẹẹ ya mi lowo ni owo mọto nigba ti wọn n lọ niyẹn, ẹ ẹ ri i pe iṣẹ Ọlọrun wa yii, awamaridii ni. Titi di bi mo ṣe n wi yii, n ko ti i ta irẹsi awọn Ṣinkafi tan o, nitori awọn ọrẹ mi naa ko yee ra si i.

O fẹrẹ jẹ pe emi ni mo ra gbogbo irẹsi ti awọn yẹn n tori ẹ jaya, bi mo si ti n ko o ni mo n ju owo sinu akaunti wọn, nitori awọn ti wọn n raja ko fowo jẹ mi niya, wọn n sanwo naa silẹ ni. Ki ẹ waa wo iṣẹ Ọlọrun, awọn ti mo n ta irẹsi fun, niṣe ni inu wọn n dun, ti wọn ni mo gba awọn lọwọ abuku ati iṣoro, pe emi o le mọ iru oore nla ti emi ṣe fawọn. Bẹẹ owo nla la n ta a fun wọn o. Awọn Alaaji Ṣinkafi ni tiwọn fẹrẹ sọ mi di Ọlọrun, wọn ni kinni naa ti di eegun ẹja si awọn lọrun, koda awọn ti n ro pe awọn ti ṣọọti ni, ki Ọlọrun too ran mi sawọn.

Iyẹn ni pe niṣe ni inu awọn ti mo n raja lọwọ ẹ n dun, inu awọn ti mo n ta a fun n dun, inu emi naa funra mi n dun, nitori gbogbo wa la n ri owo nla. Bi Ọlọrun ṣe ri niyẹn. Owo to wa nile lọwọ mi bayii, n ko ri iru ẹ ri laye mi. Koda emi naa ko mọ iye ẹ, mo kan mọ pe ko jẹ ile alaja mẹwaa meji la fẹẹ kọ si ibi ti ara ilẹ si yii, a o kọ ọ ti a oo tun gba ṣenji. Ṣugbọn loju ẹsẹ naa ni mo ti pinnu pe bi inu mi ṣe dun yii, bẹẹ naa ni mo maa mu inu gbogbo awọn ti wọn sun mọ mi dun, ọkọ mi ni yoo si ṣaaju, ohun to ba fẹ ni n oo ṣe fun un.

Lẹyin naa lo kan Safu, nitori mo n tẹnu mọ ọn, akorede ọmọ gbaa ni. Akorede gbaa ni o. Lati ọjọ to ti da ẹsẹ ẹ wọ inu ṣọọbu mi, niṣe ni oore n yi lu ara wọn fun mi. Boya ti irun to n ki ni o, boya ti keu to mọ ni o, boya aisiki Ọlọrun lo si pọ lara rẹ to bẹẹ, emi naa ko le sọ, ṣugbọn mo ri apẹẹrẹ imọlẹ Ọlọrun ninu aye ẹ. Nitori ẹ ni mo ṣe pinnu, bi oore yii ti to, bẹẹ naa ni oore ti n oo ṣe fun un yoo ṣe to. Odidi mọto kan ni, ati llẹ pulọọti meji, ohun to ba wu u ni ko fi i ṣe, n oo si tun fun un lowo ti yoo fi ra aṣọ tabi ohun to ba fẹ. Tiẹ to bẹẹ o ju bẹẹ lọ.

Sẹki naa yoo gba, nitori ko si ohun ti mo n ṣe lẹyin ẹ. Oun naa kuku tiẹ mọ, ohun to ba fẹ naa ni n oo ṣe fun un. Boya owo ti mo ba fun un, iṣẹ ile ẹ ni yoo fi ṣe, nitori lati igba to ti bẹrẹ iṣẹ ile yẹn, ko rowo ṣe nnkan sara ẹ mọ. Ko sọ fun mi o, ṣugbọn mọ mọ pe kinni naa n ba a finra. Ko si owo lọwọ ọkọ ẹ mọ, nigba ti iṣẹ to n ṣe ko lọ deede, asiko Korona yii tiẹ le fun un diẹ, ọpẹlọpẹ pe o ti ni ajẹṣẹku nilẹ. Aisan iyawo ẹ naa tun da kun un, mo si mọ pe ọpọlọpọ bukaata ti wọn n gbọ nile wọn, titi dori ounjẹ, Sẹki lo wa nidii ẹ, ṣugbọn ko jẹ fẹnu ara ẹ sọ. Lara ẹkọ ile to ni niyẹn, ko jẹ ṣe nnkan fọkọ ẹ ko sọ fẹnikan, o ni emi iya oun loun fi jọ.

Amọ mo ti pinnu pe ohun yoowu ti mo ba fẹẹ ṣe fawọn eeyan mi, inu ile ni n oo ti bẹrẹ. Nitori ẹ lo ṣe jẹ nigba ti a n pada bọ lati ọdọ lọọya nijọ naa, ṣọọbu la pada si. Emi o gba iwe kuro lọọfiisi lọọya, mo ni ki wọn ko o dani nibẹ fun mi, to ba ya mo n bọ waa gba a. Ṣọọbu la gba lọ, ọjọ ti n lọ diẹ ka too de, ṣugbọn Safu ni afi ka ṣa debẹ, Nigba ti a debẹ, awọn ọmọ ti n mura ile, lo ba ni kawa mẹtẹẹta wọle, ka kọkọ lọọ gbadura si Ọlọrun, adura ọpẹ. Ohun ti a si ṣe niyẹn, Safu naa lo ṣaaju adura, lo kewu lọ bii ilẹ bii ẹni, niṣe ni Sẹki n wo ẹnu ẹ.

Nibẹ naa ni mo ti ni ki awọn ọmọ lọọ ra waini wa, ki wọn tun ra sitaoutu, ki wọn si ra miniraasi, wọn ra paali sitaotu kan, wọn ra kireeti miniraasi, wọn ra waini igo mẹfa, la ba ru u si mọto, o dile. Ni mo ba ni ki Sẹki ba mi pe gbogbo awọn iyaale mi pata nigba ta a dele, ko pe Aunti Sikira naa. Bi gbogbo wa ṣe pade lọdọ Alaaji niyẹn, baba naa jokoo lo n bẹyin kẹẹ! Alaaji laiki faari to ba ri i pe gbogbo awọn iyawo oun lo pe ju, bii pe nnkan ẹṣọ nla kan lo ra sile ni yoo maa ṣe. Niṣe lo n wo wa ti inu ẹ n dun. Nigba ti gbogbo wọn ti jokoo tan, ni mo ba kunlẹ, mo ni emi ni mo pe wọn.

Mo waa ṣalaye ọrọ ilẹ naa fun wọn, mo ni a ti ra  a, o si ti bọ si i, ki gbogbo wọn ṣadura fun mi o. Bi Iyaale wa agba ṣe han ọrọ naa pọnkan niyẹn, awọn ni wọn kọkọ ṣadua, wọn ṣadura titi, omi si n ja bọ loju wọn. Iya Dele naa ṣe, ko too waa kan Alaaji. Aunti Sikira lo ni oun ko le fẹnu lasan ṣadura, ẹni ba fẹẹ gbadura aa gbe ọti adura kalẹ. Ni Sẹki ba sare jade, lo mu Chikelu, ọmọ ọkan ninu awọn Ibo ile wa dani, bi wọn ṣe ko awọn ọti ta a ra wale jade niyẹn. Bi awa funra wa ṣe bẹrẹ pati nile wa laarin ara wa niyẹn. Ni Iya Dele n ge sitaotu ta a wi yii, bẹẹ ni Alaaji! Waini launti Sikira n mu.

Nibi yii ni mo ti n ronu pe wahala maa ṣẹlẹ lalẹ yii o, awọn iyawo mejeeji lo n rọọṣi waini ati sitaotu yii, Alaaji funra ẹ lo n kibọn yii, ta lo fẹẹ yin in fun ninu wọn. Mo mọ pe bo jẹ Iya Dele lo gba mu, bo si jẹ Aunti Sikira ni, gobe niyẹn, ẹni ti ọwọ Alaaji ba tẹ ninu wọn, yoo ṣe kisa ibasun fun un. Bi mo ṣe n ronu ni Safu waa fi ẹnu ko mi leti, lo ba ni, ẹ maa lọ si yara yin o, mo fẹẹ ṣe were fun gbogbo awọn iya yii! Lo ba wọle lọ. Ko pẹ lo tun yọju si palọ, lo ba ni, ‘Dadi, Alaaji, ẹ waa ba mi wo kinni yii!’ Bi Alaaji ti wọle ni mo gbọ gbaga! Nigba naa ni ọrọ Safu ye mi.

O to eyi ti mo ti n sọrọ yii lo ba tun yọju, lo ni, ‘Alaaji ni ẹ ṣe o, pe o daarọ niyẹn o!’ Afi gbaga lo tun tilẹkun. Ni gobe ba ṣẹlẹ ni palọ! Mo ri Aunti Sikira to lanu, mo ri Iya Dele to faju ro. Mo yaa dide pọnkan, koju ma ribi, gbogbo ara loogun ẹ. Aunti Sikira naa dide, o fa waini ẹ, o tun gbe igo kan mi-in si i, Ọlọrun ma jẹ ko mu ara ẹ pa. Iya Dele ko tete mọ eyi ti yoo ṣe. Bi gbogbo ẹ ṣe tuka ree, ti mo ri i pe mo gbadura lẹnu awọn iyaale mi. Mo ṣi maa fun wọn lowo o, eleyii kan jẹ ajẹtẹlẹ lasan ni.

Leave a Reply