Lanlọọdu ati getimaanu pa ọmọọdun mẹrin, wọn yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo

Faith Adebọla
Diẹ lo ku kawọn araalu tinu n bi dana sun baba getimaanu kan nigba ti aṣiri oun ati ọga rẹ, Ọgbẹni Emmanuel, tu pe awọn ni wọn ṣeku pa ọmọkunrin ọmọọdun mẹrin kan, ti wọn si yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, DSP Abiọdun Wasiu, ṣalaye pe ijọba ibilẹ Lapai, nipinlẹ ọhun, niṣẹlẹ yii ti waye.
Ba a ṣe gbọ, lati ọjọ mẹrin sẹyin ni wọn ti n wa ọmọdekunrin naa, wọn lawọn obi ẹ ran an niṣẹ lati ra eelo ọbẹ wa lọmọ ọhun fi dẹni awati, ti ko sẹni to foju kan an mọ.
Ṣugbọn lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii, ni wọn ri baba sikiọriti to da ọlọkada kan duro, o ni ko gbe oun lọ sọna odo nla kan to wa lagbegbe naa, o si gbe apo kan dani.
Ọlọkada naa loun ro pe aṣọ tabi ẹru kan lo di sinu apo ọhun, ṣugbọn nigba to maa bọọlẹ lori ọkada, ọlọkada ri ipa ẹjẹ to ro sara ọkada rẹ, niyẹn ba figbe ta pe kawọn eeyan to wa nitosi waa wo iru ẹran ti ọkunrin yii di sapo to fẹẹ lọọ sọnu sodo.
Bi aṣiri ṣe tu ree, oku ọmọkunrin ti wọn ti n wa naa ni wọn ba ninu apo ọhun, wọn ti yọ oju, eti, ọkan, ati nnkan ọmọkunrin ẹ, korofo ẹ lasan ni wọn fẹẹ lọọ sọnu sodo.
Nigba tọwọ iya dun baba naa, o jẹwọ pe oun ati lanlọọdu oun ti wọn porukọ ẹ ni Emmanuel lawọn ji ọmọ naa gbe, lanlọọdu oun lo pa a, to si yọ awọn ẹya ara ẹ, o loun fẹẹ lo wọn. O lọgaa oun loun fẹẹ lọọ ba ju oku ọmọ naa sọnu.
Ibi ti wọn ti n lu baba naa lalupamokuu, ni awọn ọlọpaa de ba wọn, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e, ni wọn ba mu un lọ si teṣan wọn. Bakan naa lawọn ọtẹlẹmuyẹ wa lanlọọdu naa lawaari, wọn ti mu oun naa.
Wasiu ni iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply