Lanre Gentry, ọkọ Mercy Aigbe tẹlẹ, ṣegbeyawo alarede

Faith Adebọla, Eko

 Igbeyawo alarede mi-in ni ọkọ gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni tẹlẹ, Mercy Aigbe, Ọgbẹni Lanre Gentry, fi rọpo ajọṣe lọkọ-laya oun ati obinrin naa. Gentry ni inu oun ti dun bayii, oun ti pade ayọ tuntun nigbesi aye oun lẹyin ọdun meje ti wọn ti pin gaari.

Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ni ọkunrin naa ṣegbeyawo alarinrin pẹlu ololufẹ rẹ tuntun, Oluwabusayọ, niṣeju awọn mọlẹbi tọkọ-taya naa ti wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ ọhun.

Ninu ọrọ ṣoki kan to ba awọn oniroyin sọ lẹyin igbeyawo naa, Lanre sọ pe ko si nnkan babara ninu keeyan tun igbeyawo ṣe, o loun ti mu suuru gidi, odidi ọdun meje loun fi wa lai ni ẹnikan tori oun o fẹẹ ṣe aṣiṣe toun ṣe ninu igbeyawo oun ati Mercy Aigbe mọ.

O ni: “Tiyawo kan ba file ọkọ ẹ silẹ fun ọdun meje gbako, ṣe ko yẹ ki ọkunrin naa fẹ ẹlomi-in ni. Bi mo ṣe maa layọ lo ja ju. Inu mi dun si obinrin to wọnu aye mi bayii, ayọ mi kun, ko si iregbe oriṣiiriṣii mọ. Ọmọ Yooba ni mi, ko si nnkan babara ninu keeyan ṣe igbeyawo mi-in. Emi o binu sẹnikẹni mọ o. Gbogbo awọn ọmọ mi pata ni mo fẹran gidi, mo si fẹran awọn iya wọn pẹlu.”

Ọmọ mi ni Michelle, iyẹn ọmọbinrin tiyaa ẹ gbe waa fẹ mi, ọmọ mi ni yoo si maa jẹ titi lọ. Lọwọ yii, mo ṣi maa bimọ si i, tori mi o ti i dagba ju ọmọ bibi lọ.

Nigba ti wọn bi i boya o ti lọọ jawe ikọsilẹ fun Mercy Aigbe, ọkọọyawo tuntun yii rẹrin-in musẹ, o ni, “ẹ ma jẹ ka sọrọ nipa iyẹn, ko sohun ti mo fẹẹ sọ nipa ẹ. Ọdun meje ti obinrin fi kẹru kuro nile ọkọ ẹ naa ti to lati kọ ọ silẹ, ikọsilẹ wo lo tun ku. Ẹ wo o, oniṣowo ni mi, emi o raaye fiimu o.”

A sapa lati ba Mercy Aigbe sọrọ lori aago ẹ lori ọrọ yii, ṣugbọn ko gbe e.

Leave a Reply